Revolution Now: Ẹgbẹ́ òṣèlú AAC lé Ṣowore àti àwọn 28 mííràn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹgbẹ oselu The African Action Congress ti le Ọmọyẹle Sowore ati awọn mejidinlọgbọn miran fun ẹsun wi pe wọn dojuti ẹgbẹ oselu naa.
Ẹgbẹ Oselu AAC gbe igbesẹ yii ni ipade gbogboogbo ti wọn se ni ilu Owerri, ni ipinlẹ Imo.
Ọkan lara awọn asaaju ẹgbẹ, Emeka Ezeife lo pe fun ki wọn le Sowore ati awọn mejilelọgbọn miran kuro ninu ẹgbẹ, ti awọn ọmọ ẹgbẹ to kun naa si faramọ.
Ezeife to bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Sowore to pe fun iyipada isejọba lorilẹede Naijiria, ni Sowore ati awọn ẹgbẹ lẹyin rẹ ti mu itiju ba ẹgbẹ oselu naa.
Lẹsẹkẹsẹ naa ni wọn yan Leonard Nzenwa gẹgẹ bi adari ẹgbẹ oselu tuntun.









