Eid-el Kabir: Aisha Buhari lọ Hajj pẹ̀lú ìyàwó Ààrẹ Niger, Senegal, Gambia

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Muhammadu Buhari má a padà sí ìlú Abuja ní Ọjọ Kejidinlogun, Osù yìí lẹ́yìn Ìsinmi ọdún ilẹ́yá.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ti de si ilu rẹ ni Daura lati lo se ọdun Sallah, ti a mọ si ọdun Ileya, lẹyin ti o kuro ni ilu Abuja ni Ọjọ Kẹsan, Osu yii.

Aago marun un irọlẹ ni ọkọ ofurufu aarẹ balẹ ni papakọ ofurufu Malam Umar Musa Yar'adua ni ipinlẹ Katsina.

Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari ati igbakeji rẹ, Alhaji Mannir Yakubu pẹlu awọn to wa ki aarẹ kaabọ si ile ni papakọ ofurufu ipinlẹ naa.

Ọjọ kejidinlogun, Osu yii ni aarẹ yoo pade si ile aarẹ ni ilu Abuja saaju iburawọle fun awọn minisita tuntun ti wọn sẹsẹ yan.

Bakan naa ni iyawo aarẹ Buhari, Aisha Buhari fi si oju ikansiraẹni Instagram rẹ pe oun wa ni Mina pẹlu awọn iyawo aarẹ orilẹede miran ni Afirika lati lọ se Hajj.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Aisha wa gbadura fun alaafia ati itẹsiwaju fun awọn orilẹede lagbaye.

Àkọlé fídíò, Oro Festival: Àwọn olórò ní ọdún Màgbó ló ń gba ibi lọ, kó ire wọlé ní Ikorodu