#WhereIsEspiritDCorp: Ohun tó kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sí ẹ́lòmíì lọ̀rọ̀ yìí lórí ayélejára

Awọn ọlọpaa to ku

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Police Force

Àkọlé àwòrán, Ikọlu ọlọpaa ati ologun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oju opo Twitter ti kun pitimu nipa ero awọn ọmọ Naijiria lori ibeere ti ileesẹ ọlọpa ilẹ wa n bi ileesẹ ologun pe, ki wọn salaye bi ọlọpa mẹta se di ero ọrun lati ipasẹ ibọn tawọn ologun yin mọ wọn niluu Takum, ni ipinlẹ Taraba.

Awijare tileesẹ ologun fisita lori isẹlẹ naa ni pe, awọn ro wi pe ajinigbe lawọn ọlọpaa ọhun, eyi lo jẹ ki awọn dabọn bo wọn.

Ileesẹ ologun ati ọlọpaa ti n tako ra lori idi tawọ̀n ologun se yinbọn pa ọlọpa naa ati araalu kan lasiko ti wọn gbe gbajumọ ajinigbe kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ti dasi ọrọ naa lori ayelujara bayii, bawọn kan ti n daro awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, lawọn miiran n dẹbi ru awọn ologun ati aarẹ Muhammadu Buhari.

@bdexibojo ni tiẹ sọ pe, ile iṣẹ ologun loun wa lẹyin wọn nitori awọn lo n gbogun ti awọn agbesunmọmi, ti wọn si n fi ẹmi wọn lelẹ fun orilẹede Naijiria.

O ni ohun kan tawọn ọlọpaa mọ ni lati maa ge ẹmi awọn ọdọ kuru kaakiri orilẹede Naijiria.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

@MakemeslayC kọ nkan to da bi ewi lori ọrọ yii, o ni ologun pa ọlọpaa, ọlọpaa n pe awọn ologun lapaniyan loju opo Twitter.

O ṣalaye siwaju si pe, ile iṣẹ ọlọpaa ni irọ ni awọn ologun n pa pe o ṣeeṣi ni, o pari rẹ pẹlu aworan Aarẹ Muhammadu Buhari nibi to ti n ta eyin.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Favour Onyeoziri sọ pe iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni, o ṣalaye pe tawọn ologun ba n yinbọn pa ọlọpaa, a jẹ wi pe kawọn oloṣelu ti wọn maa n lo ọlọpaa ati awọn ologun gẹgẹ ẹṣọ kiyesara.

Onyeoziri fikun ọrọ pe, ọpọlọpọ ohun to n lọ lorilẹede Naijiria lo pe fun ki ijọba gbe igbesẹ lori wọn, ki wọn lee dẹkun wọn.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ibeere ni Ikemba 1 fọrọ naa beere ni tiẹ. O ni iyalẹnu lo jẹ f'oun pe ile iṣẹ ọlọpaa le sọ pe ile iṣẹ ologun n huwa ta ni yoo mu mi.

O ni idunnu lo jẹ f'oun pe oun wa laaye nigba ti iru iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ papaa julọ iha ti ile iṣẹ ọlọpaa kọ si iṣẹlẹ ọhun.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Epe rabandẹ ni @legendarylekzzy fi ranṣẹ si awọn ọlọpaa, o ni Ọlọrun lo maa fiya jẹ wọn.

O sọ pe asiko yii ni wọn ṣẹṣẹ mọ irora ti awọn ọmọ Naijiria maa ni ti iru iṣẹlẹ bayii ba ṣẹlẹ si wọn.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Skip X post, 6

End of X post, 6

Skip X post, 7

End of X post, 7