Oyo House: Ilé ìgbìmọ̀ Ìpínlẹ̀ Oyo buwọ́lu ìyànsípò kọmíṣọ́nà mẹ́rìnlá àtàwọn míì

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oyo State House of Assembly
Ile igbimọ aṣofin Ipinlẹ Oyo ṣayẹwo fun awọn kọmiṣọna mẹrinla ti Gomina Ṣeyi Makinde fi orukọ wọn ranṣẹ sile, bẹẹ ni wọn si buwọ lu iyansipo gbogbogbo wọn.
Orukọ awọn mẹrinla naa ni Gomina Makinde fi ṣọwọ si ile, ti adari ile Ọgbẹni Adebo Ogundoyin, si ka a nibi ijoko ile to waye lọjọbọ.
- Lórí ìmọ̀ràn Sunday Igboho, Ẹlẹbubọn ní yóò dára kí Yorùbá padà sí àmúlò èròjà ìbílẹ̀ fún ààbò
- Buhari yóò búra wọle fún àwọn mínísítà
- Sowore takú, kò jẹun ní àgọ́ ọlọ́pàá torí májèlé - Deji Adeyanju
- Òṣùká kékeré kò rẹrùn àgbà, orílẹ́èdè Nàìjíríà ṣòro púpọ̀ láti darí - Ibrahim Babangida
- Ìjọba Buhari ń wùwà bíi ìjọba Abacha lórí ọ̀rọ̀ Ṣoworẹ- Ṣoyinka
Mẹrin lara awọn eeyan to fẹ jẹ kọmiṣọna naa ti jẹ asofin ri, awọn eeyan naa ni Ọgbẹni Kehinde Ayoola (adari ile tẹlẹ ri), Amofin Adeniyi Farinto, Iyaafin Funmilayo Orisadeyi (oun nikan lobinrin) ati Ọgbẹni Muyiwa Jacob Ojekunle.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oyo state house of Assembly
Awọn miiran ni Oloye Bayo Ojo, Dokita Bashir Abiodun Bello, Ọjọgbọn Oyelowo Oyewo, Ọjọgbọn Dawud Sangodoyin, Ọgbẹni Olasunkanmi Olaleye ati Ọgbẹni Adeniyi Olabode AdebisiAdebisi.
Awọn to ku ti ile fọwọ si iyansipo ni Ọgbẹni Raheem Abiodun Abdulraheem, Ọgbẹni Seun Asamu, Dokita Wasiu Olatunbosun ati ỌgbẹniAkinola Ojo.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oyo State House of Assembly
Diẹ lara wọn to sọrọ lẹyin ti ile fọwọ si iyansipo wọn gẹgẹ bi kọmiṣọna sọ pe, awọn ri iyansipo awọn gẹgẹ bi anfani lati sin awọn eeyan ipinlẹ Oyo ati lati kopa ninu iṣejọba rere, eyi ti Gomina Ṣeyi Makinde ṣeleri fawọn eeyan ipinlẹ naa.
Bakan naa, ile tun buwọlu iyansipo Ọmọwe Nureni Adeniran gẹgẹ bi alaga igbimọ to ri si eto ẹkọ kariaye nipinlẹ Oyo, State Universal Basic Education Board(SUBEB), ti Ọgbẹni Akeem Oladeji ati Ọgbẹni Dayo Ogungbenro si jẹ ọmọ igbimọ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oyo State House of Assembly
Adari ile, Asofin Debọ Ogundoyin, ninu ọrọ tiẹ ṣapejuwe gbogbo awọn kọmiṣọna tile buwọlu iyansipo wọn naa, gẹgẹ bi awọn to kọṣẹ mọṣẹ ti wọn si jẹ olori pipe ẹda ninu iṣẹ ti wọn yan laayo.
Gomina Makinde yoo ṣe ibura fun gbogbo wọn laipẹ.












