Operation Amotekun: Amotekun dé! Ìgbáradì yóò gbérasọ l'Ekiti lọ́jọ́ Àìkú tó ń bọ̀

Aworan Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, Western Nigeria security network

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Amọtẹkun dee! Ọga ajọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Brig. Gen Joe Komolafe ti kede pe awọn to ti forukọ silẹ fun eṣọ naa pe wọn yoo bẹrẹ

igbaradi lọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2020.

Ọgagun Komolafe ni ọdunrun un eeyan le mẹẹdogbọn(325) lo wẹ yan kain-kain ninu awọn igba eeyan le ni ẹgbẹrun mẹta(3,261).

O ṣalaye pe fasiti ipinlẹ Ekiti to wa ni Ifaki-Ekiti ni igbaradi naa yoo ti waye fun ọsẹ mẹta gbako.

Ọgagun Komolafe kilọ fawọn ọdaran to wa ni ipinlẹ Ekiti pe ki wọn lọ tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nitori Amotekun ti gberasọ.

O ni ọgbọnjọ oṣu kẹsan Ọjọru ni ọjọ to kẹyin tawọn to forukọ silẹ naa ni lati de si ibi igbaradi ọhun.

Ọgagun Komolafe sọ pe lẹyin igbaradi ni wọn yoo gbe awọn to ti forukọ silẹ kaakiri ipinlẹ Ekiti lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eto alaabo mii.

A kò lè gbà kí ìjọba àpapọ̀ ṣ'agbátẹrù Amotekun, ìjọba ilẹ̀ Yorùbá yarí

Ajọ to n ri idagbasoke awọn ipinlẹ Yoruba (Development Agenda for Western Nigeria Commission), DAWN ti tako ọrọ ti oludamọran Aarẹ Muhammadu Buhari sọ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu sọ pe ọga agba ọlọpaa ni yoo sọ bi ìkọ Amotekun yoo ṣe maa ṣiṣẹ.

Shehu ni alakalẹ ọga ọlọpaa ni Naijiria ni ìkọ Amotekun yoo duro le lori.

Shehu ṣalaye pe awujọ ni Amotekun yoo ti maa ṣiṣẹ, nitori awọn awujọ yii gan an lo ni Amotekun.

Oludamọran Aarẹ ni alakalẹ kan naa ni ọlọpaa agbegbe ti ijọba apapọ fẹ da silẹ laipẹ yoo maa tẹle.

Amọ, oludari ajọ DAWN to n ri si idagbasoke awọn ipinlẹ Yoruba, Ọmọwe Seye Oyeleye ni ko sọrọ kankan ninu gbogbo ohun ti Garba Shehu sọ kalẹ.

Ọmọwe Oyeleye ṣalaye pe ile igbimọ aṣofin mẹfẹẹfa lawọn ipinlẹ Yoruba lọ ṣe agbekalẹ ofin idasilẹ Amotekun.

O ni oun ko mọ ohun ti Garba Shehu n sọ pẹlu pe ọga agba ọlọpaa ni yoo ṣagbatẹru bi Amotekun yoo ti maa ṣiṣẹ, ayafi to ba jẹ pe ofin ọga ọlọpaa gaju ofin awọn ipinlẹ Yoruba lọ loku.

Oyeleye ni idasilẹ Amotekun ko le ṣe idiwọ fun eto ọlọpaa agbegbe ti ijọba apapọ fẹ da silẹ.

Bakanna ni oludamọran fun Gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ aabo, Alhaji Jimoh Dojumo sọ pe bi Amotekun yoo ṣe maa ṣiṣẹ wa ninu ofin to gbe e kalẹ.

Ọgbẹni Dojumo ni ọrọ ti Shehu sọ fihan pe kọ mọ nipa ofin to da ikọ Amotekun silẹ.

Àkọlé fídíò, 'ìjà ṣẹlẹ̀ láàrín èmi àti ọ̀gá mi ní Lebanon tórí mi ò lè dá N300K padà'

Ẹ̀yin gómìnà, Ifá nìkan ló le tọ yín sọ́nà láì kùnà lórí Amotekun - Babaláwo

Akoda Awo kin Sunday Igboho lẹ́yìn pé ìṣẹ̀ṣe nìkan ló le ṣe ètùtù láti dẹ́kun ọ̀dàlẹ́ nínú Amotekun

Dandan ni pe ki ijọba beere lọwọ awọn babalawo lori ọrọ Amọtẹkun, bii bẹẹ kọọ, eto naa ko le kẹsẹjari.

Babalawo kan niluu Ibadan, Oloye Idowu Olukunle Adewole, Akọda Awo nijọba ibilẹ Ọna Ara lo kin ọrọ ti Oloye Sunday Adeyemo lẹyin bẹẹ.

Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lo sọ ninu fidio BBC Yoruba pe, awọn to ba fẹ darapọ mọ ikọ Amọtẹkun gbọdọ maa fi Ogun bura.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Babalawo Adewole ni fifi Ogun bura wa lara awọn ilana ti awọn to ba fẹ darapọ mọ ikọ Amọtẹkun gbọdọ tẹle gẹgẹ bi Sunday ṣe sọ.

Akoda Awo sọ pe, eto to dara ni idasilẹ Amọtẹkun, amọ ko le si aṣeyọri kankan nibẹ, ayafi ti awọn babalawo ba daa si ọrọ naa lati ṣe atọna ijọba.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

O ni Ifa nikan lo le ṣalaye ọna ti wọn le rin ti wọn ko fi ni kuna, Akoda Awo ni lọdọ awọn babalawo si ni Ifa wa.

Babalawo Adewole ni awọn babalawo lo mọ itumọ aye, o ni ilana ẹsun musulumi ati kristẹni ko le mu eto naa kẹsẹ jari.

''Iṣẹṣe lagba, iṣẹṣe lo ni ile aye, babalawo nikan lo le ṣe etutu ti ọdalẹ ko fi ni raye wọ arin ikọ Amọtẹkun,'' Akoda Awo lo woye bẹẹ.

Lórí ìmọ̀ràn Sunday Igboho, Ẹlẹbubọn ní yóò dára kí Yorùbá padà sí àmúlò èròjà ìbílẹ̀ fún ààbò

Ọkan lara awọn agbaagba ilẹ Yoruba Ifayemi Ẹlẹbubọn sọ pe, imọran gidi ni Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho gbekalẹ lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ, lori ọna lati gbogun ti awọn Fulani to n da eto aabo wa ru lawọn ipinlẹ Yoruba.

Sunday Igboho ṣalaye pe, oun atawọn eeyan kan ti setan lati lọ koju awọn Fulani, ṣugbọn awọn ọba alaye atawọn agbaagba ilẹ Yoruba gbọdọ fọwọ si pe, awọn lo ran awọn niṣẹ, ki omi maa ba tẹyin wọgbin lẹnu.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Nigba to n sọ ero rẹ lori imọran naa, Ẹlẹbubọn ni ọrọ ti Sunday Igboho sọ ṣe pataki nitori ''igi kan ko le dagbo ṣe igbo, aja to ba si lẹni lẹyin ni p'ọbọ, ẹnikan ko le maa ṣe ohun kan, ko maa lawọn eeyan to n ti lẹyin.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹlẹbubọn ṣalaye pe, ọrọ ti Sunday Igboho sọ yii pe fun apero awọn agbaagba Yoruba nitori ''ti eeyan yoo ba jagun, ọrọ lo n bẹ nidi rẹ, t'eeyan o ba si ni jagun, ọrọ naa ni n bẹ nidi rẹ.''

Yemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Yemi Elebuibon

O fikun ọrọ rẹ pe, lataye baye ni ajinigbe, ole, agbesunmọmi ati awọn ọdaran mii ti wa, ṣugbọn ilu kọọkan nilẹ kuotu ojiire lo ni nnkan iṣọra ti ogun ko fi ni ja ilu.

Ẹlẹbubọn wa ke pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba lati ṣatunṣe ''awọn eto ogun ko jalu to wa nilẹ Yoruba kọọkan'', o ni ''ọrọ eto aabo to mẹhẹ ti gba iṣọra ati ifura bayii.''

Sunday Adeyemo

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho

Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori awọn ajinigbe nilẹ Yoruba

Agba awo naa ṣalaye pe, ijọba le maa faramọ kawọn ipinlẹ lo ọna ibilẹ lati jagun awọn ajinigbe nitori ko si ninu iwe ofin orilẹede Naijiria, ṣugbọn alatiṣe ni yoo mọ atunṣe ara rẹ.

Ẹlẹbubọn ni o ṣe pataki ki Yoruba pada si awọn nnkan iṣẹnbaye nitori ẹsin ti gba ọpọlọpọ nnkan danu lọwọ ẹya Yoruba.