Ikorodu Festival: Àwọn olórò ní ọdún Màgbó ló ń gbá ibi lọ, kó ire wọlé ní Ikorodu
Awọn ọdun kan wa to so tọkunrin-tobinrin papọ nilẹ Yoruba, amọ omiran wa ti obinrin ko gbọdọ foju ri.
Iru ọdun to yọ awọn obinrin silẹ yii ni ọdun oro jẹ ọkan ninu wọn nitori igbagbọ Yoruba ni pe obinrin kii fi oju kan oro, bibẹẹkọ, oro yoo gbe.
Lasiko ọdun oro ni ilu Ikorodu ti BBC Yoruba peju si, Oloye Kazeem Adeniyi Roga salaye pe, igi ìto ni yoo sọ fun awọn pe akoko ọdun oro, ti wọn n pe ni Màgbó ti to, ti igi naa yoo si wọwe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Ọjà Àgbáláta ní Badagry rèé, níbití ẹran ejò ti dùn ju ẹran adìẹ lọ
Oloye Roga ni ti awọn oloro ba ti se etutu wọn tan, ni igi yii yoo tun ruwe pada, ti ohun gbogbo yoo si tuba tusẹ.
O ni ọdun Magbo maa n ko ibi kuro ni ilu ni, ti yoo si ko ire wọle, bẹẹ ni ilu yoo tuba, tuṣẹ laisi ewu.
- A kò mọ̀ọ́mọ̀ pa ọlọ́pàá mẹ́ta, aráàlú kan, ó ṣèèsì ni, ajínigbé la pè wọ́n - Iléeṣẹ́ ológun
- Sowore àti àwọn ọmọ ẹgbẹ Revolution Now kò ṣẹ̀ ṣófin lórí ìwọ́de, ẹ tú wọn sílẹ̀ - NLC
- Òṣùká kékeré kò rẹrùn àgbà, orílẹ́èdè Nàìjíríà ṣòro púpọ̀ láti darí - Ibrahim Babangida
- Sowore ṣèpàdé pẹ̀lú Nnamdi Kanu láti dojú ìjọba Nàíjíríà bolẹ̀ - Àjọ DSS
- Ilé-isẹ́ Ológun gbọdọ̀ sèwádìí bí ọmọogun se pa ọlọ́pàá - Buhari
Amọ awọn obinrin to ba wa sọrọ lori ọdun oro naa lo faraya pe, ọdun naa n tẹ ẹtọ awọn mọlẹ lasiko ti wọn ba n se e, to si maa n sọ awọn si igbekun ati ẹwọn.
Wọn ni kii jẹ ki awọn raye lọ sẹnu isẹ oojọ awọn, koda awọn ko ni lee lọ se idanwo tabi se ohunkohun.
Awọn obinrin naa wa gba awọn oloro yii niyanju lati maa se oro wọn lọganjọ oru dipo ọsan gangan, eyi ti ko ni di awọn lọwọ lati lọ sẹnu isẹ abi okoowo awọn.