Soyinka: Ohun gbogbo ti dẹnu kọlẹ̀ la ṣe gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀ pàjáwìrì

Rotimi Akeredolu n fun Wole Soyinka ni ẹbun

Oríṣun àwòrán, @Opetuyii

Yoruba ni agba ti ko ba kẹun sọrọ, yoo kẹ itan sare nitori agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ.

Idi ree ti ilumọọka alami ẹyẹ agbaye, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka fi n lọgun pe aarẹ orilẹede yii, Mohammadu Buhari pe yoo dara ko kede pe nnkan ko fararọ lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lẹka eto aabo, ti ohun gbogbo si ti dẹnu kọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Soyinka, ẹni to mu igbe yii bọnu lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Akurẹ nibi ayẹyẹ kan, tun salaye pe o n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de, amọ laye ode oni, oju ni wọn n mu to, nitori eto aabo ti mẹhẹ nilẹ Kaarọ Oojire kọja sisọ, o si yẹ ko wa nkan se nipa rẹ.

Rotimi Akeredolu n fun Wole Soyinka ni ẹbun

Oríṣun àwòrán, @Opetuyii

"Oniruuru ọna ni eto aabo fi mẹhẹ, paapa nipinlẹ Ondo, to si tun jẹ ohun ibanujẹ nla yika orilẹede Naijiria, nitori naa, igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere laa ti lọọ, idi si ree taa fi gbọdọ gbe igbesẹ pajawiri lati rẹyin aifararọ eto aabo naa."

Soyinka ni iwa isekupani ni aimọye ọna ti gba akoso ni gbogbo ọna lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ti iwa ijinigbe naa ko si gbẹyin, wọn si ni ma fi oko mi sọna, ọjọ kan bayii ni eeyan maa n kọ ọ.