Kukah Vs Buhari: Bíṣọ́bù Kukah ní ìfowóṣòfò lásán ní okoòwò tí ẹnikẹ́ni bá ṣe ní Nàíjíríà

Aarẹ Buhari pẹlu Biṣọbu agba Mathew Kukah

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti koro oju si ọrọ ti Biṣọbu agba ijọ aguda ni ẹkun Sokoto, ẹniọwọ Matthew Kukah sọ nilẹ Amẹrika.

Mattew Kukah lo ni iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti kuna lati dẹkun ipenija abo to mẹhẹ, eyi to tako ileri to se lọdun 2015.

Biṣọbu Kukah sọrọ naa lasiko to n ṣe idanilẹkọ kan lori bi awọn agbebọn ṣe n dojukọ awọn Kristẹni ni Naijiria, paapaa lagbegbe ariwa. fun ajọ ẹtọ ọmọniyan Tom Lantos Human Rights Commission ni ilu Washington DC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu fi sita ni ibanijẹ nla lo jẹ pe Ẹniọwọ Kukah naa lee maa tọ ipasẹ awọn eeyan kan to ni wọn n wa ipo ni ijọba.

Ileeṣẹ aarẹ fi ẹsun kan Biṣọbu Kukah pe o n gbin eso ikorira ati wahala laarin awọn ọmọ Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

O ni o dun ni lọkan jọjọ pe Ẹniọwọ naa lee maa sọ ọ jade lẹnu pe ifowojona lasan ni idokoowo yowu ti ẹnikẹni ba ṣe lori ohun amuludun bayii laarin orilẹede Naijiria ati Niger.

Ijọba ni irufẹ ohun amuludun bẹẹ to waye laarin orilẹede Naijiria ati Benin Republic ti mu ayipada ba ajọṣepọ ọrọ aje orilẹede mejeeji

Ninu ọrọ rẹ to sọ niwaju awọn aṣofin agba naa, Ẹniọwọ Kukah tọka si bi iwa ijinigbe ṣe n gogo si, ti awọn agbebọn naa si n ko ogun ja ilu, ti wọn si n gba ẹmi lẹnu tọmọde tagba.

O fi kun un pe ọpọ igba ni wọn n ṣe eyi labẹ iboju ẹsin, eyi to ni o to akoko fun awọn musulumi tootọ lati dide ji giri si bi ọrọ ṣe n lọ naa, ki wọn si yọ awọn kanda inu irẹsi wọnyii danu, ki wọn to ba ẹsin jẹ mọ wọn lori.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Ileeṣẹ aarẹ ni irọ pata gbaa ni ohun ti alagba Kukah tun sọ pe, ṣe ni awọn kawọ gbera lori bi awọn agbebọn Fulani ṣe n pa awọn agbẹ kiri.

O ni ọwọ iṣejọba Buhari ni ilana akọkọ lori ọrọ awọn agbẹ ati darandaran ti waye lorilẹede Naijiria.