Yomi Fabiyi: Èmí ló mú Bimpe Oyebade dé agbo tíátà àmọ́ ó dà mí

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/mo_bimpe/Instagram
Gbaju gbaja osere tiata nni, Yomi Fabiyi ti fesi pada lori ẹsun inawọ ifẹ sira ẹni, ti oserebinrin kan fi kan.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin nipa bi Adebimpe Oyebade, toun naa jẹ osere tiata, se fi ẹsun kan Yomi Fabiyi pe ko lo oun ninu ere tiata mọ nitori pe oun ko gba, ko ba oun lopọ.
Nibayi, lasiko to n fọrọ werọ pẹlu iwe iroyin Punch, Yomi Fabiyi ni nitori pe oun jẹ osere tiata, ko tumọ si pe oun ko gbọdọ ni ero ifẹ si obinrin.
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Ta ló ní kí Adebimpe Oyebade bóra nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ Nollywood?
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Adebimpe gba omijé lójú Adedimeji, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí da Saheed àti Fathia pọ̀
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
- ''Àwa àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi nitori Baba Ijẹsha''
O ni sebi Bimpe wa bii ara awọn ololufẹ oun ni, ti oun si fun ni ipo asaaju kan ninu ere sinima ti oun n se lọwọ nigba naa.
"Kii se pe mo se idanwo fun lati mọ bi yoo se yege si, bẹẹ ni ko tọ mi wa pe oun fẹ wa kọ isẹ tiata, koda mo ti pari idanwo ohun ti mo n se fawọn to fẹ sisẹ.
Amọ mo se iwuri fun nipa fifun ni ipo to lagbara ninu sinima naa ."
Yomi ni ohun to sadede mu ki oun yi iwa pada si oserebinrin naa ni pe oun gan gan lo sẹ oun, koda, o mọ ohun to se si oun pẹlu.
"Gẹgẹ bi ọkunrin, maa ri obinrin ti ọkan mi nifẹ si amọ mo dupẹ pe ko ni mo fi tipa ba oun lopọ, tori ko si ofin to sọ pe mo gbọdọ fun ni ipa lati ko ninu awọn sinima ti mo ba n gbe jade.
Iru ẹtọ wo lo ro pe oun ni gan, to fi maa ro pe o di dandan ki oun ko ipa ninu awọn sinima ti mo n gbe jade, ma si salaye idi to fi sẹ mi."
Yomi ni oun ni oun mu Bimpe Oyebade de agbo osere tiata lọdun 2015, ti oun si jẹ ko kopa ninu sinima oun kan nigba naa.
Amọ ni ọjọ ti wọn pari yiya sinima naa tan, ni Bimpe lọ, ti ko si boju wẹyin mọ lati igba naa, osu Kinni ọdun 2019, eyiun ọdun mẹrin lẹyin naa, ni oun ati ẹ tun to foju kanra.
"Laarin ọdun mẹrin naa, Bimpe ti ya sinima mẹta ọtọọtọ, n ko mọ oun to wa laarin rẹ ati awọn eeyan to n se onigbọwọ mi, pẹlu alakoso sinima pẹlu awọn ayaworan naa.
Ohun ti mo kan gbọ ni pe o n gba ẹyin lọ seto bi yoo se ya sinima lẹyin mi, iru aya nini wo ree?
Emi ni mo mu Bimpe de agbo tiata nitori mo fẹ ko di ilumọọka oserebinrin. Mo fẹ ko ni isẹ lọwọ amọ ki lo de to n gba ọna ẹburu kaakiri?
Lẹyin o rẹyin, lo wa pe mi pe oun ni isẹ fun mi, mo si sọ fun pe ẹni to gbe isẹ fun gan, ipasẹ mi lo se mọ, ti n ko si gbe isẹ fun onitọun mọ titi laelae."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
- Ọmọ Elebuibon tó jẹ́ òṣèré tíátà àti ìyá awo figbe ta lórí ìdẹ́yẹsí tó ń kojú - Oyin Elebuibon
- Ẹ̀yin aṣọ́bodè, ẹ yé ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀ mọ́, agbègbè wa kìí ṣe ibùdó ogun - Olu ti Igboora
- À kò ní le è máa káwọ́ gbera mọ́ nípa àwọn ìkọlù ìgbà gbogbo nílẹ̀ Yorùbá- Gani Adams
- Inú mi dún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún nǹkan ti mo da- Mary Daniel
- Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè
- Àwọn aṣọ́bodè ní fàyàwọ́ làwọn lé wọ Igboọra, kìí ṣe agbébọn Fulani
- Ìpínlẹ̀ Eko fi oṣù mẹ́ta kún ìjọ̀kó àwọn tó ń gbẹ́sùn ìṣekúpani lásìkò ìwóde EndSARS
Yomi Fabiyi wa n gbarata pe gbogbo awọn egungun ẹyin oun lagbo tiata ni Bimpe Oyebade gba mọ oun lọwọ lai fi to oun leti.
O ni to ba jẹ pe o bi oun ni, oun ko ni di lọwọ lati lo wọn, amọ ki lo de to n ji oun ti kii se tiẹ?
Gbajumọ osere naa fikun pe ọpọ nnkan lo tun waye laarin awọn mejeeji amọ to ba fẹ, o le maa yi wọn mọ alaye pe nitori oun ko gba fun oun lati ba oun lopọ ni.
"Ki ọkan eeyan fa mọ ẹnikan yatọ si ki eeyan se asemase pẹlu ẹnikan. ẹ le bi Bimpe leere to ba jẹ nawọ ifẹ si mi tabi idakeji rẹ?
N ko kuku kọkọ kofiri rẹ tẹlẹ, oun lo kọkọ kọbi ara si mi. Yatọ si eyi, agbalagba ni awa mejeeji. Ohun to si se pataki ni pe a ko fi tipa tipa se e.
O yẹ ka le la awọn ọdọ lọyẹ pe nini ifẹ si ẹnikan yatọ si sise asemase pẹlu eeyan kan. A n sọrọ nipa sise asemase pẹlu eeyan kan, oun n sọrọ pe mo dẹnu ifẹ kọ oun, se iyẹn mu iwa ori pipe dani?





















