Oyin Elebuibon: Olórìṣà ni mí, ẹ yé é fi ojú ẹni ibi wo àwa ẹlẹ́sìn àbáláyé

Oyin Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Instagram/oyin elebuibon

Osere Yoruba, Oyinkansola Elebuibon ti pariwo sita pe ẹlẹsin abalaye ni oun, kii ṣe Musulumi tabi Kristiẹni.

Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Elebuibon sọ pe Oriṣa ni oun n sin.

"O ni Olorisa ni mi, ohun naa ni ma a si jẹ ni igba gbogbo."

O ṣalaye pe jijẹ ẹni to n sin Orisa kii ṣe iwa ọdaran, bẹẹ ni kii ṣe ibi, nitori pe inu gbogbo eniyan ni ibi n gbe."

Oyinkansola Elebibon tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn to jẹ ẹlẹsin ibilẹ, lo jẹ baba ati iya to bi gbogbo ẹsin to ku, "nitori naa, ẹ jawọ ninu didẹyẹ si awọn ẹlẹsin ibilẹ.

Ọrọ ti Oyin Elebuibon kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, oyinelebuibon/Instagram

Ko tan sibẹ o, o ni ofin gan-an daabo bo ominira ẹsin ati didarapọ mọ ẹgbẹ to ba wu eeyan.

Ẹ fi wa silẹ ka sin Orisa wa, ati awọn alaalẹ wa ni ọna to ba wu wa.

Ilẹ Yoruba kii ṣe ilẹ Araabu, arọmọdọmọ Orisa ni wa."

Àkọlé fídíò, Ifayẹmi Elebuibon: Ọ̀pọ̀ òkú ló ń rìn káàkiri ìlú Èkó, Ìbàdàn, Òṣogbo

Taa ni Oyinkansola Elebuibon?

Oyinkansola Elebuibon jẹ ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja babalawo, to tun jẹ Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon.

Oṣere tiata Yoruba ni, to si n gbe ni orilẹ-ede America.

Yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun n ṣe iṣẹ agbohunsafẹfẹ ati oludari eto nibi ayẹyẹ.

O kẹkọọ gba iwe ẹri ninu imọ Ọsin ẹranko ati ilera wọn, ni Federal University of Technology, FUTA, nilu Akure, nipinlẹ Ondo.

O si tun jẹ Iya Awo, to ma n difa fun awọn eeyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laipẹ yii ni iroyin kan sọ pe oṣerekunrin, Lateef Adedimeji, lo bi ọmọ rẹ to bi laipẹ yii fun. Ṣugbọn, o ti sọrọ jade pe irọ̀ patapata ni iroyin naa.

Ẹsin ibilẹ tabi abalaye ṣi wa ni awọn ẹbi ati ilu nilẹ Yoruba, bo tilẹ jẹ pe awọn to tẹwọ gba a ko pọ.