Igangan attacks: Olu ní ìlú Igboora, Igangan, Ayete kìí ṣe ààlà Nàìjíríà, kí aṣọ́bodè dẹ́kun ìpànìyàn níbẹ̀

Awọn osisẹ asọbode

Oríṣun àwòrán, NCS

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Seyi Makinde ti kede pe awọn awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣọbode lo kọlu Igangan lọjọ Ẹti, kii ṣe awọn agbebọn.

Gomina Makinde sọ eyi ni ibamu pẹlu ohun ti Olu ti Igboọra, Ọba Jimoh Ọlajide Titiloye ati alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, Adeoye Adedoyin fi to ikọ ojumi too, ti ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ.

Ọba Jimọh Titiloye ni ṣe ni gbogbo awọn olugbe ilu Igboọra atawọn ilu miran to yii ka n sa kijokijo, ti olukuluku si n fọn lugbẹ lasiko ikọlu naa eleyi to gbẹmi olori awọn ẹṣọ amọtẹkun lagbegbe naa atawọn meji miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A fẹ sọọ ki gbogbo agbaye mọ pe awọn ilu wa, Igboọra, Igangan ati Ayetẹ kii ṣe ilu to wa ni ibode tabi aala orilẹede yii.

Ki lo de tawọn ẹṣọ aṣọbode maa fi wa sọ ilu wọn di ibudo itajẹsilẹ ati ogun?"

Àkọlé fídíò, Flying car: Ọkọ̀ tí ń fò, ọ̀nà àbáyọ kan rèé sí ìṣòro 'go slow' lágbègbè rẹ

Olori ikọ ti ijọba ran lọ si agbegbe naa, Kọmiṣọna ọlọpaa to ti fẹyinti, Sunday Odukọya ke sawọn eeyan agbegbe naa lati dakundabọ fiyedenu ki wọn ma si ṣe fa wahala.

Odukọya to jẹ amugbalẹgbẹ agba fun gomina Makinde lori ọrọ abo ni, awọn eto abo alajumọṣe laarin awọn fijilante ilu atawọn oṣiṣẹ alaabo bi Amọtẹkun, yoo so eso rere lagbegbe naa.