Lizzy Anjorin: Fún ayẹyẹ ọdún kan ìgbéyàwó wọ́n, ọkọ Lizzy fi ọkọ̀ tá lọ́rẹ

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Oṣerebinrin Lizzy Anjorin ṣẹṣẹ de lati ilẹ okeere to ti lo ṣe ayẹyẹ ikọmọ ọmọ rẹ tuntun jojolo, ti orukọ rẹ n jẹ Florida.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oṣerebinrin Lizzy Anjorin ti gbadura fun ọkọ rẹ to si dupẹ lọwọ rẹ fun ọkọ bọgini to fi ta lọọrẹ fun ayajọ ọdun kan ti wọn ṣe igbeyawo.

Oju opo Instagram rẹ ni Anjorin ti fi aworan ati fidio ọkọ tuntun naa han fun awọn ololufẹ rẹ.

Anjorin-Lawal to ṣeṣẹ pada de si orilẹede Naijiria lẹyin to rin irinajo ọlọjọ pipẹ lati ṣe ikomọ ọmọ rẹ jade ni awọn ilu kaakiri agbaye.

O dupẹ lọwọ rẹ fun ẹbun iyebiye yii to si bẹrẹ si ni gbadura fun kikan-kikan.

Ọkọ Anjorin, Lawal lo fi ọwọ bo oju rẹ to si mu lọ si idi ọkọ tuntun naa, eleyii to ya lẹnu to si bẹrẹ si ni jo ijo ayọ.

Ko to de idi ọkọ naa ni ọkọ rẹ ti bo oju rẹ, pe ọrẹ rẹ kan to ti pẹ to ti ri wa ni ita lati wa ki ku ayẹyẹ.

Bi o ṣe n lọ naa lo n bere pe tani ẹni to wa nita tabi iya oun to wa lọrun ni'?

Wẹrẹ to de idi ọkọ naa, lo bẹrẹ si ni wo si otun si osi lai mọ wi pe lootọ oun lo ni ọk tuntun naa, ti ọkọ rẹ si fi da loju pe oun lo ni i.

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Instagram

''Ẹ wa naa, ta lo ni ọkọ yii, ẹ ti rogo!, ọkunrin tun ti yamilẹnu lẹẹkan si!'', to si fo si oke lati fi idunnu rẹ han.

''Aye ko ni da aarin Mr Lawal ati Lizzy Anjorin ru''

Lẹyin eyi lo sọ si ori ikunlẹ, ti Anjorin si bẹrẹ si ni dupẹ lọwọ ọkọ rẹ fun ẹbun ọkọ bogini naa.

''A dara fun Mr Lawal, a ṣe oriire, ẹmi ọla a gun, Baba Florida! oju oni ti yin, aye o ni ya ẹyin ati Lizzy Anjọrin ka.''

Ni Osu Keje, ọdun 2020 ni Anjorin ati Lawal ṣe igbeyawo eleyii to sọ wọn di lọkọ-laya.

Laipẹ naa ni awọn mejeeji di ayọ abarabintin lẹyin ti Anjorin bi ọmọ tuntun jojolo, ti wọn pe orukọ rẹ ni Florida.

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Instagram

Bakan naa lo bẹrẹ si ni ki ọmọ tuntun rẹ ni mẹsan mẹwa nitori o sun lasiko ti gbogbo awọn eniyan n ki wọn ku oriirẹ ayajọ ọjọ igbeyawo wọn to pe ọdun kan.

Awọn eniyan bẹrẹ si ni gba ti Anjorin lẹyin to ṣe fiimu to pe akọle rẹ ni Owo Naira Belt, ti awọn eniyan si gboriyin fun iṣẹ takuntakun to ṣe naa.

Awọn fiimu miran ti Anjorin tun ti gbe jade ni Olani Gbarada, Gold, Iyawo Abuke, Kofo Tinubu, ati Kofo De First Lady.