Hajj 2021: Nkan kò rí bí ti tẹ́lẹ̀ ní Hajj ọdún 2021 ní Saudi

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Eero perete lo n yipo Kabbah lẹẹkan naa, tako bi ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ṣe ma n yipo rẹ lọdọọdun tẹlẹ.

Awọn arinrinajo ti n de si ilẹ mimọ Mecca ti fun eto Hajj ọdun 2021.

Irinajo mimọ Hajj keji re e to waye lati igba ti Covid-19 ti bẹrẹ, botilẹ jẹ pe awọn to kopa lọdun yii ju ti ọdun 2020 lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹrun lọna ọgọta ọmọ orilẹ-ede Saudi Arabia to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 wọn pe nikan si ni wọn fi aaye gba lati kopa ninu eto Hajj, ninu eeyan ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹta din mẹwaa eeyan to forukọ silẹ lati kopa lorilẹ-ede naa.

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣaaju ibujade aarun Covid-19, eeyan to le ni miliọnu meji lati awọn orilẹ-ede agbaye lo ma n kopa ninu irinajo Hajj lọdọọdun.

Awọn ti yoo kopa ti gbọdọ gba abẹrẹ lẹẹmeji, ọjọ ori wọn si gbọdọ wa laarin ọdun mejidinlogun si marundinlaadọrin, ti ko ni aisan nla kankan lara.

Diẹ lara awọn aworan re e lati ọdọ awọn to ti de ilẹ Mimo fun Hajj ọdun 2021, nibi ti wọn ti n duro de ọkọ ti yoo gbe wọn lọ si mọṣalaasi nla ilu Mecca.

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn alaṣẹ to n mojuto irinajo mimọ naa sọ pe gbogbo eto aabo ilera ni awọn ṣamulo lọdun yii.

Wọn ni, wakati mẹta-mẹta ni eeyan ẹgbẹrun mẹfa n wọle si ilẹ mimọ lati ṣe eto adura tawaf.

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Eero perete lo n yipo Kabbah lẹẹkan naa, tako bi ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ṣe ma n yipo rẹ lọdọọdun tẹlẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Hisham al-Saeed sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ti abala eeyan kọọkan to wọle ba ṣe n jade, ni awọn n fin oogun apakokoro sinu ile mimọ naa, ki awọn miran to wọle.

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ilana titakete si ara ẹni wa lara nkan gboogi ti awọn alaṣẹ orilẹ-ede Saudi Arabia mu ni dandan ni Hajj ọdun 2021

Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta eeyan ni Covid-19 ti mu ni Saudi Arabia, o si ṣeku pa eeyan ẹgbẹrun mẹjọ.

Awọn arinrinajo Hajj ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, AFP