Saudi Arabia Hajj 2020: Alaga Hajj ni Naijiria ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé.

Àkọlé fídíò, Saudi Arabia Hajj 2020: Alaga Hajj ni Naijiria ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé.

Alaga Ajọ Hajj ni Naijiria, Alhaji Zikrullah Hassan ti ni ọpọlọpọ awọn to yẹ ki wọn lọ fun Hajj lọdun yii ni inu wọn kodun lẹyin ti ijọba ilẹ Saudi gbegile Hajj ọdun 2020.

Alhaji Hassan lasiko Ifọrọwanilẹnuwo parọwa si awọn eniyan lati gba bẹẹ lọdun yii nitori ati dẹkun ajakalẹ arun Coronavirus ni.

Bakan naa lo wa kesi awọn eniyan ti wọn fẹ gba owo wọn pada lati yọju si wọn.