Nigeria Insecurity: Àwọn ọdọ́ Arewa ké sáwọn aṣáájú láti pe ìpàdé àjọ tó ńi ìrònú lórí Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, other
Ipe kan ti lọ sọdọ awọn adari orilẹede Naijiria pe ki wọn dide giri lati daabo bo orilẹede Naijiria, ki o ma baa dawo.
Ẹgbẹ awọn ọdọ kan lapa oke ọya NYLF ṣalaye pe ki awọn aṣiwaju wọnyii wa ọna lati pe ipade ironu laarin ara wọn, ki wọn lee wa ojutu si isoro to nkoju orilẹede Naijiria.
Bakan naa lẹgbẹ NYLF ke si Aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, olori ijọba ologun tẹlẹ, Ibrahim Babangida ni wọn ni ko ṣaaju ijiroro naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àṣírí márùn-ún tí obìnrin kò gbọdọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀
- Wo obìnrin tó ní ojú ara méjì, ilé ọmọ méjì àti ẹsẹ̀ mẹ́rin
- Gómìnà mẹ́ta láti Òkè Ọya ń dírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ àgbà Yorùbá fún Buhari
- Ìdí tí mo fi ń gbẹjọ́ rò fún Baba Ijesha - Amofin Ogala
- Háà! Ẹ wò ó bí ayé ṣe le mọ́ wa ní Afghanistan - Aráàlú figbe ta
- Mo bú sẹ́kún nígbà tí mo gba owó oṣù gelemọ àkọ́kọ́ ní Saudi-Arabia - Dokita
- "Ìbínú aráàlú ń bọ̀ lọ́dọ̀ gómìnà tó bá gbé ilẹ̀ wa sílẹ̀ fétò ìdaranjẹ̀"
- Èèkàn amúlúdùn méjì jáde láyé láàrín ọjọ́ méjì síra wọn
- Obìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ lé ní 60 dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó jì ẹ̀ṣọ́ ara òkú
- Ìmáàmù àgbà orílẹ̀èdè Ghana gbé owó kalẹ̀ fún kíkọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
Ẹgbẹ awọn ọdọ apa oke ọya naa tun rọ awọn eekan bii Theophilous Danjuma, Abdulsalami Abubakar, Oloye Earnest Sonẹkan atawọn miran, lati ko ipa to jọju ninu irufẹ apero bẹẹ. lọna ati koju ipenija to n koju orilẹede Naijiria.
Alaga apapọ ẹgbẹ naa, Elliot Afiyo ṣalaye nilu Abẹokuta, lẹyin ifikuluku pẹlu oloye Ọbasanjọ pe kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ijinigbe ati ọrọ aje to dagun, n da Naijiria laamu.
Bakan naa lo ni ijẹkujẹ, ipe fun ipinya wa lara awọn ipenija to n koju Naijiria lọwọ, eyi lo si mu ko di ọranyan fawọn olori wọnyii lati dide wa ọna abayọ si awọn ipenija naa.
Ẹgbẹ naa ni ododo ọrọ to koro ni pe, ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba ko ni ipinnu ati eroja oṣelu to yẹ lati koju ọpọ ipenija to n ba Naijiria finra, bakan naa lo fi kun un pe ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu ni iṣoro dukuu laarin ara wọn, leyi to fẹ ki oloye Ọbasanjọ ba wọn da si.
Ẹgbẹ naa ni awọn wa lara awọn ẹgbẹ to fọnrere ibo fun aarẹ Muhammadu Buhari ki o to ja jo awọn loju pe, aṣiyan patapata ni awọn yan, ti awọn si gbọdọ gbe igbesẹ atunṣe gbogbo to ba yẹ.














