Victor Uwaifo: Èèkàn amúlúdùn méjì, Sir Victor Uwaifo àti Victor Olaotan jáde láyé

Oríṣun àwòrán, other
Agba akọrin, Sir Victor Uwaifo ti jade laye lẹni ọgọrin ọdun lọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2021.
Ọjọgbọn ninu iṣẹ orin naa jẹ gbajumọ kaakiri agbaye pẹlu gẹgẹ bi ogbontagi onigita ara ati fere fifọn.
Omilẹgbẹ ami ẹyẹ ni Sir Victor Uwaifo gba nigba aye rẹ nilẹ yii ati loke okun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo obìnrin tó ní ojú ara méjì, ilé ọmọ méjì àti ẹsẹ̀ mẹ́rin
- Obìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ lé ní 60 dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó jì ẹ̀ṣọ́ ara òkú
- Wo ìdí tí Ìje ṣe ṣe pàtàkì nílùú Ijare lẹ́yìn tí ọba bá wàjà
- Olórí ijọ kan àti Olùjọ́sìn mẹ́sàn án ko ìjàmbá ọkọ̀ nílùú Eko
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
Awọn orin rẹ bii 'Mami water', 'Joromi', ati 'Guitarboy', kun ara awọn awo orin rẹ to gbajumọ julọ kari aye.
Bakan naa ni Sir Vitor Uwaifo jẹ akọrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ Member of the Order of Niger, MON ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria.
Ni bayii oniruuru awọn eekan lagbaye ni wọn ti n daro rẹ.
Aarẹ Buhari ninu ọrọ idaro rẹ ni gbogbo orilẹede Naijiria ni yoo ṣafẹri Sir Victor Uwaifo gẹgẹ bi ẹni to fi ipa manigbagbe lele ni gbogbo ọna ẹda titi kan ẹka ẹkọ ati iṣakoso.
Eekan elere itage, Victor Ọlaotan naa jade laye.
Ẹwẹ, Eekan elere itage, Victor Ọlaotan naa jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrin.
Ọlaotan gbajumọ pupọ fun ipa to ko ninu ere ọlọsọọsẹ ni Tinsel.
Ọdun marun un ni ijamba ọkọ kan to ni, fi daa wolẹ ko to jade laye.
Ibudo yiya sinima agbelewo kan lo n lọ lọdun 2016, nigba to fi kagbako ijamba ọkọ naa.
Iyawo rẹ, arabinrin Julia Ọlaotan to kede iku rẹ, wa dupẹ pupọ fun igbe aye rẹ, to si ni ko rọrun ki eeyan wa loju kan naa fun ọdun marun un. "asiko to fun un lati lọ sinmi bayii"
Ninu ọrọ idaro to kọ nipa Victor Olaotan, gbajumọ elere tiata ni, Richard Mofe-Damijọ (RMD) ni bi o ti wu oun to, pe ki awọn olufẹ wa mase jade laye, paapaajulọ awọn elere itage, "sibẹ iranti wọn ko ni parẹ kuro lọkan wa."


















