Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya

Ọkunrin ati Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ibalopọ laarin tọkọ-taya ṣe jẹ nkan to gbajumọ, naa ni ọpọ ko ni imọ to o nipa rẹ.

Eyi to si n ṣe idiwọ ati idena fun bi wọn ṣe n gbadun ibalopọ si .

1. Fun apẹẹrẹ, awọn eeyan kan gbagbọ pe ibalopọ pẹlu ọkọ tabi aya wọn nikan yoo su wọn to ba ya. Ti wọn si gbagbọ pe nini ibalopọ pẹlu ẹlomiran ni ọna abayọ.

Irọ patapata ni eyi. Nini ibalopọ pẹlu ọkọ tabi iyawo rẹ nikan kun fun igbadun, bi o ba fẹ ko ribẹ. Iwadii fihan pe bi igbeyawo ba ti sẹ pẹ si, ni adun ibalopọ ibẹ ma n pọ to.

Idi si ni pe tọkọ-taya to mọ riri igbeyawo wọn, fi inu tan ara wọn debi i pe wsn ma n sọ nkan ti wọn ba fẹ ninu ibalopọ fun ara wọn.

Bakan naa ni sisun mọ ara wọn fun iye ọdun ti wọn ti fi ṣe igbeyawo yoo fun wọn ni anfaani lati gbadun ibalopọ.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

2. Irọ patapata ni pe awọn ọkunrin ma n fẹ ibalopọ ju obinrin lọ.

Idi ni pe ọpọ awọn obinrin mii fẹran ibalopọ ju ọkunrin lọ. Kii sẹ pe awọn obinrin kii poungbẹ tabi fẹran ibalopọ to yaayi; o kan jẹ pe àṣà ko faaye gba wọn lati ma a sọ sita.

Yatọ si eyi, o rọrun fun ara ọkunrin lati tete dide fun ibalopọ ju obinrin lọ. To si jẹ pe iṣẹlẹ kekere le pa adun ibalopọ mọ wọn lara.

Àkọlé fídíò, Joke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá

3. Ibalopọ ati ọrọ sisọ jọ n ṣiṣẹ papọ ni

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ki obinrin sun silẹ, ki ọkunrin ni ibalopọ pẹlu rẹ ni ibalopọ gidi. Rara o.

Yoruba sọ pe, ẹni to ba dakẹ, tara rẹ yoo ba a dakẹ.

Ẹnikẹni to ba fẹ ẹ gbadun ibalopọ pẹlu ọkọ tabi aya rẹ gbọdọ la ẹnu sọ fun ẹnikeji rẹ, iru nkan to fẹ lasiko ibalopọ, awọn nkan ti yoo mu ko gbadun ibalopọ, ati ọna to fẹ ki ẹnikeji gba tẹ oun lọrun.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

4.Ọpọ ọkunrin lo tun gbagbọ pe awọn lo gbọdọ lewaju lasiko ibalopọ gẹgẹ bi olori ile, ti obinrin si gbọdọ tẹriba labẹ aṣẹ.

Eyi ko dara rara. Isi ni pe ojuṣe tọkọ-taya ni ọrọ ibalopọ wọn jẹ. Itẹlọrun ati igbadun si ni yoo ti ẹyin rẹ yọ, ti awọn mejeeji ba jọ ṣiṣẹ pọ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Nitori naa lo ṣe dara ki awọn ọkọ rọ awọn iyawo wọn lati ma a sọ bi wọn ṣe fẹ ki ọkọ wọn ba wọn lopọ.

Titẹ ara ẹni lọrun gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo le jẹ aṣiri ati ọna abayọ si ibalopọ to nitumọ.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

5.Awọn kan tun gbagbọ pe nigba ti nkan ọkunrin ba dide ni ibalopọ bẹrẹ. Irọ o, eyi ko ribẹ rara. Ibalopọ to nitumọ bẹrẹ fun obinrin ṣaaju asiko naa.

Fifi ọwọ pa a lara, ati fifi ifẹ han jẹ diẹ lara awọn eroja ibalopọ fun obinrin.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku