Grazing Researves: NINAS fọnmú pé ìfẹ̀hónú hàn tó kò ṣẹlẹ̀ rí ń bọ̀ lórí gbígba ilẹ̀ fún ìdaranjẹ̀ lẹ́kùn gúúsù

Darandaran to n fun awọn maalu ni omi mu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni awifunni ko to da ni, agba ijakadi ni, bẹẹ si ni ogun awitẹlẹ kii pa arọ.

Idi ree ti ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajijagbara miran lẹkun guusu Naijiria fi n ke tantan lori ofin idaranjẹ tuntun ti ijọba fẹ gbe jade.

Awọn ẹgbẹ ajijagbara ni guusu Naijiria naa, ti wọn wa labẹ aburada Nigeria Indigenous Nationalities Alliance for Self Determination (NINAS) ti wa fi atẹjade kan sita lori ofin idaranjẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to si wa labẹ aburada ẹgbẹ NINAS naa ni ẹgbẹ Ilana Omo Oodua atawọn ẹgbẹ miran lati ẹkun ila oorun ati aarin gbungbun guusu Naijiria to fi mọ Middle Belt.

Ninu atẹjade naa si ni NINAS ti n leri leka pe gomina to ba fi ilẹ awọn silẹ lẹkun guunsu Naijiria fun eto idaranjẹ ti ijọba apapọ n gbero fawọn Fulani yoo ri ibinu araalu.

Àkọlé fídíò, Joke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá

Ẹgbẹ NINAS ni iwọde ati ifẹhonu han araalu ti ko tii waye ri, ni iru gomina to ba gbe ilẹ rẹ kalẹ yoo foju wina rẹ, lawọn ipinlẹ to wa lẹkun guusu Naijiria.

NINAS, ti alagba Banji Akitoye jẹ alaga fun, ti Tony Nnadi si jẹ akọwe apapọ rẹ, lo ti wa n fi ewe ọmọ mọ awọn gomina ipinlẹ to wa labẹ aburada ẹgbẹ naa leti pe ki wọn tete gbọran.

Bakan naa ni wọn n dunkoko pe gomina to ba fi ẹsẹ bata ilẹ kan silẹ fun ijọba apapọ lati gbe kalẹ fun Fulani, yoo fi ika hanu nigbẹyin ni.

"A wa n rọ awọn gomina wa lati bọwọ fun ero araalu lori igbesẹ yiya ibudo kan sọtọ fun eto idaranjẹ Fulani eyi ti ijọba apapọ se.

A ko dunkoko mọ yin, amọ a n rọ yin ni pe gomina to ba gbe ilẹ wa silẹ feto idaranjẹ Fulani gbọdọ setan lati foju wina ibinu araalu to lagbara.

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Niwọn igba to jẹ pe ọpọ awọn Fulani darndaran yii ni wọn lo wa lati awọn orilẹede to mule ti Naijiria, gomina to ba wa gbe ilẹ ajogunba wa fawọn ajeji ni iwọde yoo da ipinlẹ rẹ wo de ipilẹ."

Bẹẹ ba gbagbe, ijọba apapọ lo ti fi ontẹ lu ofin kan to n fa awuyewuye eyi to se agbeyẹwo agbekalẹ ibudo idaranjẹ ọrinlelọọdunrun o din meji lawọn ipinlẹ mẹẹdọgbọn yika Naijiria.

Ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹjọ ọọdun 2021 si ni ofin naa di bibuwọlu lati ọdọ aarẹ Muhammadu Buhari.