Nigerian Doctors Crisis: Àwọn dókítà tó kúrò ní Nàíjíríà lọ sílẹ̀ UK, US àti Saudi sọ ìrírí ayọ̀ tí wọn ń ní

Awọn Dokita to n sisẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Iya kii se omi ọbẹ, Oluwa mase jẹ ka jẹ iya nile aje.

Adura yii ni awọn dokita to kuro ni orilẹede Naijiria, kọja lọ soke okun n fi se orin kọ, lasiko ti wọn tẹwọgba owo osu wọn akọkọ nilẹ okeere.

Kaakiri awọn orilẹede bii Saudi Arabia, United Kindom ati Amẹrika si ni awọn dokita lati orilẹede Naijiria fọn si nitori iya to n jẹ wọn lorilẹede Naijiria.

Awọn dokita naa, lasiko ti wọn n ba iwe iroyin Punch sọrọ salaye pe aini ohun eelo lati fi sisẹ ati owo osu tasọrẹ tawọn n gba lo mu kawọn pinnu lati gba ajo lọ sisẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba si gbagbe, lọwọlọwọ bayii, awọn dokita ni Naijiria si wa lẹnu iyansẹlodi ti wọn n se tori ẹsun ailakasi ijọba si itọju wọn ati aidahun awọn ohun ti wọn n beere fun.

Lara awọn dokita naa ni bi o tilẹ jẹ pe awọn n siyemeji ki oun to wa sisẹ lorilẹede Saudi Arabia amọ awọn ro pe o san fun awọn lati wa ju ki ebi pa awọn si Naijiria lọ.

Àkọlé fídíò, Doctors‘ Strike: Àwọn dókítà tó ń woṣẹ́ níran ní UCH sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀dùn ọkàn wọn

"Nigba ti mo kọkọ tẹwọ gba owo osu mi ni Saudi, mo bu sẹkun ni. Ẹgbẹrun lana ọgọfa din meje nairia (N113,250) ni owo osu mi ni Naijiria, ibẹ ni maa ti bọ aya, ọmọ atawọn obi mi.

Aye le koko mọ mi, ti mo si maa n tọju ẹgbẹlẹgbẹ alaisan ki osu to pari, ti isẹ si fẹẹ yi mi lọrun lasiko naa.

Amọ Saudi Arabia ni ẹgbẹrun mẹta dọla si ẹgbẹrun mẹjọ ni oun yoo san fun mi, idi ree ti mo fi gba lati kuro nile.

Alaisan mẹrin si mẹjọ pere ni mo n tọju ni ọjọ kan soso, ti wọn si tun n fun mi ni isinmi ọjọ mẹrindinlogoji laarin ọdun kan.

Iya nla ni ijọba Naijiria fi n jẹ awọn dokita, o si yẹ ki wọn yipada, bibẹẹ kọ aimọye dokita ni yoo kuro ni Naijiria lọ soke okun, ijafara si lewu pẹlu."

Iwadi kan ti wa fidi rẹ mulẹ pe ida kan ati aabọ awọn dokita to gba idanilẹkọ ni Naijiria lo gba ilẹ UK lọ laarin osu Keje si Ikejila ọdun 2020.

Amọ ni bayii, iye wọn ti fo fẹrẹ soke si ida mẹta aabọ laarin osu Kẹrin si Ikarun ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun