Doctors‘ Strike: Àwọn dókítà tó ń woṣẹ́ níran ní UCH sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀dùn ọkàn wọn

Àkọlé fídíò, Doctors‘ Strike: Àwọn dókítà tó ń woṣẹ́ níran ní UCH sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀dùn ọkàn wọn

Ọpọ awọn dokita nile iwosan UCH to ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ lasiko abẹwo wa sibẹ, ti salaye pe ewu n bẹ loko longẹ, lori bi ọpọ awọn dokita se n ya lọ soke okun.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan ijọba apapọ pe ọwo awọn dokita to sẹsẹ pari ẹkọsẹ to n ran awọn lọwọ, nijọba tun kọ lai san owo osu wọn.

Wọn fikun pe awọn ipinlẹ bii mọkandinlogun lo tun jẹ awọn dokita wọn lowo osu mẹrin si marun nigba ti ijọba si n san ẹgbẹrun marun pere gẹgẹ bii owo adojutofo fun ewu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn dokita naa wa fi ika hanu pe ijsba ati ileesẹ to n se akoso owo osu awọn osisẹ ijọba apapọ, IPPIS, ko fi orukọ awọn dokita kan soju opo ayelujara wọn, ti wsn ko si san owo osu awsn dokita naa.

O wa gba ijọba apapọ atawọn ipnilẹ nimọran lati mu idẹrun awọn dokita nibaada, bibẹẹkọ, ewu n bẹ loko longẹ lori ilera araalu.