Toll Gates Fees: Owó bodè táwọn ọkọ̀ yóò san wà láàrin ₦200 sí ₦500 fún ìrìnàjò kan

Ẹnu iloro ti wn ti n gba owo bode loju popo

Oríṣun àwòrán, FGN

Igbimọ alasẹ Naijiria ti buwọlu gbigba owo bode loju popo (Tollgate) pada lawọn opopona nla alabala meji, kaakari orilẹ-ede yii.

Awọn ọkọ aṣoju ilu, ọmọ ogun, kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta, ati ọkada nikan ni eto naa yọ silẹ.

Minisita fun iṣẹ òde ati ile gbigbe, Babatunde Fashola lo kede igbesẹ tuntun yii ni Ọjọru, lasiko to ba awọn akọroyin sọrọ lopin ipade ọlọsẹẹsẹ igbimọ alasẹ ti Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo dari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ ti ijọba gbe yii waye lẹyin bi ogun ọdun ti isejọba Olusegun Obasanjo wo gbogbo awọn ibudo ti wọn ti n gbigba owo tollgate ni Naijiria ni ọdun 2003.

Ọgbẹni Fashola sọ pe, awọn opopona ti wọn o ti ma a gba owo yii jẹ ìdá mẹrinnla ati diẹ ninu opopona ẹgbẹrun marundinlogoji to jẹ ti ijọba apapọ, to si tun jẹ abala meji.

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Owo ti awọn ọkọ yoo ma a san yoo wa laarin igba Naira si ẹẹdẹgbẹta Naira, ni irinajo kan.

O ni ni bayii ti igbimọ alasẹ ti fọwọ́ si dida sisan owó toll gate pada ni awọn opopona kan, ileesẹ ìjọba ti oun n dari ti ṣe tan lati bẹrẹ awọn nkan ti yoo sọ bi eto naa yoo ṣe tete bẹrẹ.

Sugbọn sa, Fashola sọ pe kii ṣe 'ọ̀la' (kíákíá) ni eto naa yoo bẹrẹ.

Fashola sọ pe eto naa ko ni i bẹrẹ titi gbogbo àwọn opopona ti ọrọ kàn yoo fi wa ni ipo to dara fun ọkọ̀.

Bakan naa lo sọ pe wọn yoo dunadura pẹlu awọn ileesẹ ìjọba to yẹ lori ọna ti wọn o gbe e gba."

O ni kii ṣe atunse àwọn oju popo nikan ni wọn o ma a fi owo to ba n wọle ṣe, o ni ijọba yoo tun ma a fi la àwọn ọna miran.

Ati pe ilana imọ ẹ̀rọ igbalode ni wọn o fi ma a gba owo ni tollgate, ki akoyawọ le wa.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap