Yoruba Nation: Akintoye àti èèyàn 1m fẹ́ kí àjọ UN tú ìwé òfin Nàìjíríà ká

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua
Aarẹ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akitoye yoo ṣaaju miliọnu kan eeyan, ti yoo ṣoju awọn ẹya to n beere fun iyapa lati ara Naijria, NINAS.
Ẹgbẹ naa n lọ si apejọ apapọ ajọ iṣọkan agbaye, UN loṣu kẹsan ọdun 2021 lati beere agbekalẹ ibo tawọn eeyan yoo fi sọ ero bo ya wọn fẹ yapa kuro lara Naijiria tabi wọn fẹ tẹsiwaju.
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye fi sita lọjọ Iṣẹgun.
Ẹgbẹ NINAS yoo tun sọ fun apejọ UN lati tu iwe ofin Naijiria ọdun 1999 ka.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló fa àkọ̀tun ìyapa láàrin àwọn ajìjàgbara Yorùbá Nation?
- Buhari, to bá fi pánpẹ́ ọba mú Akitoye, ohun tá ṣe rèé - Ẹgbẹ́ Ajìjàgbara ṣèkìlọ̀
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
Awọn olori oniruuru ẹgbẹ awọn ẹya to n beere fun iyapa lati ara Naijiria ti wọn wa lati apa Guusu ati arin gbungbun Naijiria, ti kọkọ fẹnuko ninu ipade lọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2020.
Ninu ipade yii naa wọn tun ti fẹnu ko pe ajọ UN gbọdọ fagile iwe ofin Naijiria ọdun 1999.
Apejọ ajọ iṣọkan agbaye UN yoo waye lati ọjọ kẹrinla si ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii.
Atẹjade naa sọ pe ẹgbẹ NINAS yoo maa kepe gbogbo awọn ẹya to wa lati apa Guusu ati aringbungbun Naijiria lati gbaruku ti ipe fun idasilẹ orilẹede ẹya wọn lara Naijiria.
Ẹgbẹ NINAS yoo tun beere nibi apejọ ajọ UN, lati fi ọmọogun apẹtu sija ranṣẹ si Naijiria lati daabo bo awọn eeyan apa Guusu Naijiria lọwọ awọn Fulani daran daran ati Boko Haram pẹlu ISIS to n pa wọn lojoojumọ.
Ọjọgbọn Akintoye, Ọjọgbọn Yusuf Turaki, akọwe agba NINAS, agbẹjọro Tony Nnadi, ati kọmiṣọnna akọkọ fun eto ẹkọ to tun jẹ alaga gbogbogbo ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Wale Adeniran lo buwọlu atẹjade naa.
Lori iroyin kan to sọrọ nipa ẹgbẹ kan to n pe fun ki wọn fofin de ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ki wọn le maa lanfaani lati pe fun ohun kohun niwaju apẹjọ ajọ UN, atẹjade naa sọ pe lorukọ ẹgbẹ NINAS yoo fi fẹhonuhan nibi apjọ naa kii ṣe lorukọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
Gbogbo awọn ẹya to wa lati apa Guusu ati aringbungbun Naijiria to n gbe nilẹ Amẹrika ni ẹgbẹ NINAS ti kepe lati darapọ mọ wọn loṣu kẹsan ti wọn ba n ṣe ifẹhonuhan naa niluu New York.


















