Yoruba Nation Agitation: Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ajìjàgbara kóra sábẹ́ àbùradà kan, Ilana Omo Oodua takété

Oríṣun àwòrán, Yoruba Nation
Yoruba ni airin lọwọọwọ ni jẹ ọmọ ejo niya, ti Ọka ba siwaju, ti Paramọlẹ tẹ le, ti Ojola wa n wọ ruru bọ lẹyin, ta lo jẹ duro de wọn.
Idi ree ti ẹgbẹ tuntun kan fi dide ti awọn oniruuru ẹgbẹ́ ajìjàgbara nilẹ Yoruba yoo wa labẹ aburada rẹ, eyi ti wọ́n pe ni Yoruba Self Determination Council.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nibi ìpàdé kan tó wáye ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹjọ ọdun 2021 ni wọ́n ti fẹnu ko lori igbesẹ naa.
Ni eyi ti wọn si da ẹgbẹ́ àpapọ̀ tuntun fawọn ẹlẹgbẹ jẹgbẹ ajijagbara nilẹ Yoruba naa silẹ.
Wọ́n ni ẹgbẹ́ tuntun yii ni yóò jẹ́ orí pátápátá fún gbogbo ẹgbẹ́ Yorùbá tó kù nílé àti lẹ́yìn odi.
Àtẹ̀jáde ti ìgbìmọ̀ kan ti wọ́n pe ni G8 fi síta lo ti ṣàlàyé ni kikun nipa re.
O ni pé, àkójọpọ̀ àwọn onímọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ̀ tuntun ti wọ́n ni ìtàkùn káàkiri àgbàyé.
O ni: Paapaa nilẹ UK àti US, ni wọ́n ti n pàmọ́pọ̀ láti ko gbogbo ọmọ Yorùbá papọ̀ ábẹ́ àsía kan.
Wọ́n ni lara ìfẹ̀nukò tó wáyé ni ibi ìpàdé náà ni láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ẹ̀dógún nínú àwọn ẹgbẹ́ àjìjàgbara tó kù, tí wọ́n yóò yàn ni ìpàdé ẹgbẹ́ tó n bọ̀.
Àtẹ̀jádè náà fi kun un pé, àwọn ẹgbẹ́ tó péjú síbi ìpàdé náà ni Ilana Omo Oodua, Yoruba World Assembly, Yoruba Ko'Ya ati Oodua Redemption Alliance.
Àwọn ẹgbẹ yooku ni Movement for Oduduwa Republic, Yoruba Global Coalition, Yoruba Global Youths.
Awon mii ni: Egbe Omo Yoruba in Europe, Global directorate, Oodua National Congress, Agbekoya, Muslim Association of Yoruba Nation, (MAYON), Yoruba Nation Christian Association (YORNCA).
Ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua ni oun ko dara pọ mọ ẹgbẹ kankan
Ní kété tí iroyin nipa agbekalẹ ẹgbẹ to gboooro yii jade sita, ni àtẹ̀jáde kan yọjú ní àdári fun ẹka ọ̀rọ̀ tó n lọ ninu ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua, Maxwell Adeleye.
Ẹgbẹ̀ Ìlànà ọmọ Oodua ni oun si ni olórí gbogbo ẹgbẹ́ Yorùbá tó n jà fún òmìnira Yorùbá.
Bakana naa lo ni ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye lo si jẹ́ olórí gbogbo ẹgbẹ́ tó n jà fún òmìnira Yorùbá àti pé oun kò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kankan tàbi yí orúkọ padà sí omíràn.
O ni kò sí ìpinu láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà kankan.
Àtẹjáde náà fi kun pé, ìpinu kan soso ti ẹgbẹ́ náà ni, ni láti gba òmìnira fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀-òòjíre, ẹgbẹ́ náà kò sì ni káàrẹ̀ nínú ìpinu rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ilé iṣẹ́ BBC Yorùbá rí àtẹ̀jáde yìí ní a kan sí ọ̀kàn lára ẹgbẹ́ tó péjú síbi ìpàdé ti wọn ti se agbekalẹ ẹgbẹ tuntun to gbooro fawọn ajijagbara, ti wọn sẹsẹ kede rẹ naa, eyi to wáye lọ́jọ́ keje, oṣù kẹjọ, ọdún 2021.
Banji Akitoye wà nínú ìpàdé tá ṣe, ìpínu wa sì sojú rẹ̀ - Deji Osibogun
BBC Yoruba kan si adari ẹgbẹ́ Yorùbá K‘ọya, tii se ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yorùbá tó péjú níbi ìpàdé tó wáyé náà.
Adarí ẹgbẹ́ naa, Deji Osibogun ṣàlàyé fún BBC Yorùbá pé, lóòtọ́ ni ìpádé yìí wáye àti pé fún ìlọ̀síwájú gbogbo Yorùbá lápapọ̀ ló jẹ ẹ lógún.
Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, Ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye wa nínú ìpadé náà, gbogbo ìpìnú àti àbá tí wọ́n dá níbẹ̀ sì ló ṣe ojú rẹ.
Ó fi kun pé àìkọ́wọ̀ọ́ rìn èjò lo n ṣekú pa wọ́n, èyí lo sì pe fún ìpàdé tó wáye lọ́jọ́ náà.
Osibogun ní ìpinu ti àwọn ṣe ni ọjọ́ náà ni ki ẹgbẹ́ gbogbo tó lé ni méjìléládọ́rin bọ́ sí abẹ́ ìdàrí ẹnì kan ṣoṣo, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye.
Adarí égbẹ́ Yorùbá K'oya fi kun pé, kò si ẹni to n pínu láti yọ Baba Akinroye nipo, nítori pe Ejòlá ni, gbogbo ọmọ ejò to kù ni yóò máa wà ní abẹ́ ìdari Akintoye.
O salaye pe nínú ìpàdé mííràn tí yóò tún wáyé lọ́jọ́ iwájú ni awọ́n yóò ti yan gbogbo àwọn olóyè tuntun tó kù..






















