Afghanistan Crisis: Ikọ̀ Taliban ba òpó iná ọba jẹ́, kò sí omi mímu, ó tún ń gé ọwọ́ afurasí olè

Ikọ Taliban

Kangun kangun kangun, o ti wa n kangun sibi kan fun awọn eeyan orilẹede Afghanistan bayii lẹyin ti ikọ Taliban gba akoso orilẹede naa.

Nibayii, awọn araalu kan ni Herat ti sọrọ soke lori igbe aye inira ti wọn n gbe lorilẹede Afghanistan lati igba ti ikọ Taliban ti gba ijọba.

Ilu Herat yii si ni ilu to tobi sikẹta lorilẹede Afghanistan, to si jẹ ẹnu bode si orilẹede Iran.

Awọn eeyan naa, ti wọn fi fọnran ohun wọn ransẹ si BBC ni, igbe aye koba-kole naa ti n mu inira nla ba awọn pupọ.

Ọkan lara awọn eeyan naa ni, se ni oun maa n di oju oun nireti pe oorun ni oun n sun lọwọ, alakala si ni oun n la lọwọ, laipẹ si ni oun yoo si laju sile aye pada.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Ikọ Taliban tun ti n ge ọwọ awọn afurasi ole:

O ni ojoojumọ ni oun n gbọ orisirisi iroyin nipa ọsẹ ti ikọ Taliban n se, ti wọn si n fi iwa ipa bawọn araalu lo.

O salaye pe ni ẹba ile oun, oun gbọ pe ika Taliban ti ge ọwọ eeyan meji lori ẹsun pe wọn ji nnkan.

Bakan naa lo ni wọn ko gba ki awọn obinrin lọ sẹnu isẹ, bi obinrin yoo ba si jade kuro nile, ọkunrin kan gbọdọ tẹ le lẹyin.

"Obinrin kankan ko si tun gbọdọ si oju rẹ silẹ, ki ẹnikẹni ri nitori o gbọdọ wọ ibori ni.

Awọn ọkunrin gan ko gbọdọ wọ asọ Jeans ati T-Shirt amọ asọ ibilẹ orilẹede Afghanistan ni ki wọn maa wọ."

Ikọ Taliban ti ba opo ina ọba jẹ, ti ko si tun si omi ẹrọ:

Ọkunrin miran to tun ba BBC sọrọ ni awọn ikọ Taliban yii tun ti n lọ lati ojule de ojule fun awọn eeyan lai naa ikede idarijin fun gbogbo eeyan ti wọn se.

O ni eleyi gan ti n ko irẹwẹsi ba awọn lorilẹede Afghanistan, to fi mọ oun gan alara, ti wọn si ni awọn akẹkọbinrin gbọdọ maa lo Hijab wa sileẹkọ ni.

"Saa kan pere lo ku ki n pari eto ẹks mi ni fasiti, n ko si fẹ ki wọn fi oun ontẹ orukọ tuntun orilẹede Afghanistan, eyiun Islamic Emirate of Afghanistan lu paali iwe ẹri mi.

Gbogbo ere ta ti jẹ lati ogun ọdun sẹyin lo ti wa sopin."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ eeyan Afghanistan lo fẹ kuro lọ si Iran, Europe atawọn orilẹede ọlaju miran:

Ninu fọnran ohun miran, obinrin mii salaye pe nigba ti ikọ Taliban ba bẹrẹ ikọlu rẹ, ko ni si ina ọba lati lo.

O ni wọn ti ba opo ina ọba jẹ, ti ko ni si ina, bakan naa ni ko ni si omi mimnu fun awọn.

O fikun pe bi o tilẹ jẹ pe ounjẹ ati oogun to to wa nilu Herat, amọ lawọn agbegbe igberiko, ọpọ isoro lo n ba wọn finra.

"O nira fun awọn eeyan lati wa si ilu nlanla, ti wọn ko si ni oogun ati ounjẹ to to, amọ wọn ti si awọn ọna to lọ sawọn igberiko yii pada ni ọsẹ to kọja.

Ẹru ti wa n ba awọn eeyan ilu Afghanistan nipa ọjọ iwaju wọn ati ọrọ aje wọn, ti wọn si ti n ta awọn ohun eelo alona wọn bii tẹlifisan ati ẹrọ amomitutu.

Awọn owo ti wọn ba tu jọ yii ni wọn fi n rinrin ajo lọ si orilẹede Iran, Yuroope atawọn ilu ọlaju miran lagbaye."

O salaye siwaju pe iporuru ọkan nipa pe nnkan le buru si ju bayii lọ ti n ba awọn araalu, ti ọpọ wọn si n ronu bi wọn yoo se jade kuro lorilẹede naa.

Àkọlé fídíò, People in Afghanistan’s third-largest city, Herat, explain how life has changed in recent weeks