Afghan - Taliban fi ado oloro pa eniyan marundinlọgọrun

Oríṣun àwòrán, AFP
O kere tan eniyan màrúndínlọ́gọ́rùn ti d'oloogbe ti awọn bii méjídínlọgọ́jọ miran si farapa ni Kabul, olu ilu Afghanistan ninu isẹlẹ ado oloro to bu gbamu ni owurọ ọjọ abamẹta.
Apaniyan to gbe ado oloro naa wa ọkọ ti o ngbe awọn alaisan kan ti wọn fi ko ado oloro eyi ti o bu gbamu kọja ibusọ awọn ọlọpaa lati kọja si opopona kan ti o wa fun awọn oṣiṣẹ ijọba nikan atawọn ile isẹ ilẹ okere.
Awọn Taliban ti sọ pe awọn ni awọn se okunfa ikọlu naa, eyi to buru ju fun ọpọlọpọ osu.
Ni ọsẹ to kọja, awọn onija Taliban pa eniyan mejilelogun ni iyara-igbafẹ hotẹẹli kan ni ilu Kabul.

Oríṣun àwòrán, Google
Awọn to soju wọn koro sọ wipe agbegbe naa to fi mo ile to wa fun awọn ofiisi ajọ isọkan agbaye, ile iwosan kan ati ibi itaja kan ti wọn mọ si Chicken street lo kun fọfọ fun ero nigba ti ado oloro naa bu gbamu. Nise ni gbogbo agbegbe isẹlẹ naa kun fun eefin.
Ẹlomii to s'oju rẹ koro, amoju ẹro lori ẹrọ ayara bi asa (ko fẹ ka da orukọ rẹ) sọ fun ile isẹ BBC wipe oun wa ni nkan bii kilomita kan si ibi isẹlẹ naa nigba to gburo ariwo ọhun. O sọ pe "mo ri eefin kiki. Eefin naa ni oorun buruku, o ko wọ inu oju mi, mi o si le riran fun igba diẹ".
O sọ wipe nigba ti oun sun mọ ibẹ, o ri ara awọn eniyan nilẹ rẹẹrẹ, o da bi iboji. "Isẹlẹ naa buru jai, agbegbe naa ti dibajẹ".

Oríṣun àwòrán, EPA
Igbakeji agbẹnusọ fun ile isẹ to nri si ọrọ abẹnu, Nasrat Rahimi sọ wipe ẹni to se ikọlu naa gba ibi ti awọn ọlọpaa ti n se ayẹwo kọja o si sọ fun wọn wipe oun ngbe alaaarẹ kan lọ sile iwosan Jamhuriat to wa ni tosi.
Ọgbẹni Rahimi sọ pe ibi ayẹwo keji ni o ti ju ado oloro naa.
Asojukọroyin BBC to wa nibi isẹlẹ naa sọ wipe ko rọrun lati kọja nibẹ. Bi wọn se nyẹ awọn ọkọ wo ni wọn nwo ohun idamọ awọn awakọ. O fi kun un wipe wọn yoo si wadii bi ẹni to se ikọlu ọhun se rọna lọ.












