Afghan Conflict: Ìjọba àti ẹgbẹ́ alákatakítí Taliban ń jíròrò lórí gbígbé ìjọba kalẹ̀

Aworan aarẹ Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe aarẹ orileede Afghanistan, Ashraf Ghani ti sa kuro nilu.

Eyi n waye bi awọn ọmọ ikọ Taliban ṣe ti de eti bebe olu ilu ilẹ naa Kabul.

Bakan naa la gbọ pe igbakeji aarẹ Amrullah Saleh naa ti sa nilu.

Wahala pọ lọrun arakunrin Ghani pe ko kọwe fipo silẹ plu bi awọn Taliban ti ṣe gba akoso ọpọ ilu nilẹ naa laarin ọjọ mẹwa pere

Aworan awọn ọmọ ogun Afghanistan ni Kabul lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun Afghanistan si n ṣakoso awọn apa kan Kabul ṣugbọn ko si ẹni to le sọ igba ti wọn yoo fi ṣakoso da

Kẹ̀rẹ̀-kẹ̀rẹ̀ Taliban ti dé ẹnu ọnà Kabul ní Afghanistan

Awọn ọmọ ikọ ẹgbẹ ajijagbara Taliban ti fẹ ẹ de olu ilu orileede Afghanistan lẹyin ti wọn gba akoso ọpọ awọn ilu nilẹ naa.

Minisita feto abẹle si ti sọ pe idunadura ti waye lati gbe ijọba kalẹ lai si itajẹsilẹ.

Atẹjade kan lati ọdọ ikọ Taliban sọ pe awọn ti paṣẹ fawọn ọmọ ogun wọn lati duro wamu lẹba olu ilu ilẹ naa.

Agbẹnusọ Taliban kan sọ fun BBC pe ''A fi da awọn eeyan Afghanistan loju pe a ko ni gbẹsan lara ẹnikankan''

Russia n gbero lati pe ipade pajawiri igbimọ alaṣẹ ajọ isọkan agbaye lati jiroro lori ọrọ Afghanistan.

Aworan awọn mọlẹbi to sa kuro lati ariwa oriuleede Afghanistan wa si olu ilu Kabul

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọkẹ aimọye ọmọ ilẹ ASfghanistan lo sa asala nitori ogun abẹle to n waye nibẹ

O ni awọn yoo ti ileeṣẹ orileede awọn to wa ni Afghanistan pa nitori ikọ Taliban ti ṣe ileri aabo fawọn.

O ti fẹ ẹ to ogun ọdun bayi ti awọn ọmọ ogun Amẹrika ti n lewaju ikọ ọmọ ogun agbarijọpọ to wa lẹyin awọn Taliban

Papa ofurufu Bagram ati ọgba ẹwọn to jina si aarin gbungbun Kabul niwọn ogoji kilomita lawọn Taliban sọ pe awọn ti gba akoso rẹ.

Aaye yi fi igba kan jẹ ibudo awọn ọmọ ogun Amẹrika to tobi julọ ni Afghanistan ki wọn to kogba kuro nibẹ laarin oru ọjọ keji Oṣu Keje.

Aarẹ Joe Biden ti sọ idi ti oun fi gbe igbesẹ kawọn ọmọ ogun Amẹrika kuro ni Afghanistan, to si ni oun ko ni awijare kankan lori ''idi ti Amẹrika yoo fi duro kanrin kese saarin ogun abẹle ilẹ mii''

Awọn eeyan to to lati gba iwe irinna ni Kabul

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ero pọ pitimu ti wọn fẹ gba iwe irina ni Kabul

Orileede Amẹrika ti nko awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ wọn to wa ni Kabul sinu baalu ologun nibi ti wọn fi awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun marun un sọwọ si wọn.

Lowurọ ọjọ Aiku ni awọn ọmọ ogun Taliban gba akoso ilu Jalalabad lai si idiwọ kankan.

Ohun ti eyi tunmọ si ni pe Taliban ti gba akoso gbogbo ọna to so Afghanistan mọ Pakistan.