ISIS: Orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ẹgbẹ́ alákatakiti Islamic State n fínna mọ́ ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn alakatakiti ẹsin Islam ti wọn n jẹ Islamic State lo kéde pe ki gbogbo musulumi agbaye darapọ mọ awọn lọdun 2014.
Eyi waye lẹyin ti wọn ti fi ẹsẹ mulẹ lorilẹ-ede Iraq àti Syria.
Olori ẹgbẹ́ naa, Abu-Bakr Al-Baghdadi lo dari ẹgbẹ naa titi to fi ku lọdun 2019, lasiko ti ilẹ America ṣe ikọlu si ibudo wọn ni Ariwa Syria.
Nigba ti yoo si fi di ọdun 2017, ẹgbẹ ajijangbara alakatakiti yii, IS, ti padanu pupọ ninu awọn ibùba rẹ ni Syria ati Iraq.
- Ẹ wo bí Hushpuppi ṣe farahàn nílé ẹjọ́ l'Amẹrika fún ìgbà àkọ́kọ́ láti jẹ́jọ́
- Bàbá Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Elérúwà àti àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá míràn tí wọ́n rọ̀ lóyè
- Ìjọba Nàìjíríà ti mú Dókítà Anu tí àwọn kan f'ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú iṣẹ́ abẹ ìdí ló n ṣe
- Erépá ní bàbá àti ìyá mi ṣe tí wọ́n fi bí mi, wọn kò fẹ́ra wọn- Funsho Adeolu
Eyi lo si fi opin si ìjẹ gàba rẹ ni agbegbe naa.
Sugbọn ṣa, Islamic State tẹsiwaju lati da awọn ẹka silẹ ni India ati Central Africa.
Lọwọ lọwọ, ẹka mẹrindinlogun ni IS sọ pe oun ni ẹka jakejado agbaye ati pe Iṣẹ ti ẹka kọọkan n ṣe si yatọ.
Diẹ lara wọn wa ni Ìwọ̀ Òòrùn Afrika.

Oríṣun àwòrán, Islamic Propaganda
Awọn orilẹ-ede ti Islamic State ti n sisẹ niyii:
Iraq:
Orilẹ-ede Iraq ni orísun ẹgbẹ alakatakiti Islamic State, ati awọn isọmọgbe rẹ.Orilẹ-ede naa si ni ẹgbẹ ajijangbara naa ti ṣe ikọlu julọ.
Ẹgbẹ al-Qaeda la le sọ pe o bẹrẹ ijijangbara ẹṣin Islam, lẹyin ti awọn ọmọ ogun America wọ orilẹ-ede naa lọdun 2003.

Oríṣun àwòrán, Islamic State Propaganda
Ẹgbẹ naa yi orúkọ pada si ISIS, ni Iraq lọdun 2006.O si tun da ISIL silẹ l'oṣu Kẹrin, ọdun 2013.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2014, lo pa orúkọ da si IS, lẹyin to dá isejọba "caliphate" silẹ, ni Syria ati Iraq.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Syria:
Ẹgbẹ IS ni ẹgbẹ alakatakiti to fẹṣẹ mulẹ julọ ni orilẹ-ede Syria, lẹyin Iraq.
Syria si ni wọn n ṣe ikọlu si ju lẹyin Iraq.
Koda, Iraq ti ibode rẹ pẹlu Syria nitori bẹ ẹ.
O si ti ṣe ọpọlọpọ ikọlu nibẹ lábẹ́ orúkọ ISIL to n jẹ bayii.
Ìwọ̀ Òòrùn Afrika (Boko Haram lo ranṣẹ pe awa Islamic State):
Oṣu Kẹta, ọdun 2015, ni IS kede pe oun ti da ẹka silẹ ni Ìwọ̀ Òòrùn Afrika.
O ni oun ṣe bẹẹ nitori bi ẹgbẹ́ agbesunmọmi to wa ni orilẹ-ede Naijiria, Boko Haram, ṣe ránṣẹ si oun.
O si pe orúkọ ẹka naa ni ISWAP (West African Islamic League).
Ipinlẹ Borno lorilẹ-ede Naijiria, orilẹ-ede Chad, Niger, Mali, Burkina Faso, ati Cameroon.
Lati igba ti wọn ti da a silẹ si ni ISWAP ti n ṣe ikọlu si awọn ọmọ ogun Naijiria. O si tun n kọlu awọn Kristẹni.
Iyapa waye ninu ISWAP lẹyin ti IS fi awọn miran rọ́pò awọn adari rẹ, Abu Bakr bin Muhammad Shekau ati Abu Musab al-Barnawi.
Shekau fa ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ́ wọle.
O si yi orúkọ ẹgbẹ rẹ to ti kọkọ da silẹ pada si Jama'at Ahl al-Sunna lil-Da'wah wal-Jihad (Boko Haram).
Sinai:
Sinai ni wọn n pe orúkọ ti awọn ajijagbara n jẹ lorilẹ-ede Egypt.
Oṣu Kọkanla, ọdun 2014, ni wọn da ẹgbẹ naa silẹ, nigba ti ẹgbẹ ajijangbara Ansar Bayt al-Maqdis to ti wa nibẹ lati ọdun 2011, jẹjẹ atilẹyin rẹ fun IS.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Sinai n kọlu awọn ọmọ ogun Egypt, ati awọn Kristẹni nibẹ.
L'oṣu Kinni, ọdun 2020, olori tuntun fun IS, Abu Hamza al-Qurashi, kede pe igun tuntun ẹgbẹ naa yoo kọlu awọn Júù ati Ísírẹ́lì.
Khorasan:
Oṣu Kinni, ọdun 2015, ni IS kede pe oun ti da ẹka silẹ ti yoo ma a ṣíṣẹ ni Afghanistan, Pakistan, ati awọn agbegbe to yi wọn ka.
Wilayat Khorasan lo pe orúkọ rẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Taliban tẹlẹ lo wa ninu ẹgbẹ Wilayat Khorasan.
Lati igba ti wọn ti da a silẹ, Khorasan ti ṣe awọn ikọlu ado oloro to pọ ni awọn ibi kan ni Afghanistan, nípa lilo awọn asaadoku mọ́ra.
Libya:
Oṣu Kọkanla, ọdun 2014, ni IS kede pe oun ti wọ orilẹ-ede Libya.
O si ti kọlu awọn oṣiṣẹ eto aabo, ileesẹ aṣoju orilẹ-ede ati ileesẹ iwe iroyin.
Ipa IS dinku lorilẹ-ede naa lẹyin oṣu Kejila, ọdun 2016, ti agbara bọ mọ lowo niluu Sirte.
Ẹgbẹ naa ti gbiyanju lati pada si Libya, sugbọn agbara rẹ ko fẹsẹ mulẹ daada mọ.

Oríṣun àwòrán, Islamic State Propaganda
Central Africa:
Wilayah Wasat Ifriqyah ni IS pe orúkọ rẹ ni orilẹ-ede Democratic Republic of Congo (DRC) ati Mozambique.
Oṣu Kẹrin, ọdun 2019, ni IS kede idasilẹ rẹ nibẹ. Oun lo si ṣe ikọlu akọkọ to pa ọpọ eeyan ni DRC.
Oṣu meji lẹyin rẹ lo ṣe ikọlu ni Mozambique.
Lati igba naa lo si ti n ṣe ikọlu si awọn oṣiṣẹ eleto aabo, Kristẹni, ati awọn ọmọ ogun ilẹ okeere.
East Asia:
Ẹ̀ka ẹgbẹ naa to wa ni East Asia tí ṣe ikọlu to pọ ni orilẹ-ede Philippines, ati Indonesia.
O si kede l'oṣu Kọkanla, ọdun 2014, pe oun ti ri atilẹyin gba ni Philippines.

Oríṣun àwòrán, others
Yemen:
Oṣu Kọkanla, ọdun 2014 lo kede pe oun ti da ẹka silẹ ni Yemen.
Ẹgbẹ naa si lo ṣe ikọlu akọkọ ni orilẹ-ede naa.
Mọsalasi kan ni asaadoku mọ́ra kan kọlu l'oṣu Kẹta, ọdun 2015.
Lati oṣu Keje, ọdun 2018, ni ìjà ti n waye laarin IS ati ẹka al-Qaeda ni Yemen.
IS fi ẹsun kan al-Qaeda pe oun satilẹyin fun ijọba orilẹ-ede Yemen lati kọjú ija si oun.

Oríṣun àwòrán, Islamic State Propaganda
Pakistan:
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun, ọdun 2019, ni wọn da ẹka IS silẹ ni Pakistan.
Sugbọn kii ṣe igba akọkọ niyẹn ti ẹgbẹ naa ṣe ikọlu nibẹ. Àmọ́, lábẹ́ isakoso Khorsan.
Oṣu Karun, ọdun 2015, ni ẹgbẹ naa ṣe ikọlu akọkọ ni Pakistan.
O si n ṣe ikọlu si awọn ọmọ ogun Pakistan, àwọn ọlọpaa, ẹgbẹ Shia, àwọn Kristẹni.
Awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara Taliban naa si n doju ogun kọ wọn ni Pakistan.















