Ọ̀gá Ọlọ́pàá: Àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ni yóò máa ṣàkósó FSARS báyìí

Ikọ SARS

Oríṣun àwòrán, @NPF_NIGERIA

Ọga agba ọlọpa tuntun lorilẹede Naijiria, Muhammed Adamu ti kede lọsan ọjọ Aje pe, oun ti se atunto ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale lorilẹede Naijiria.

Adamu, ẹni to kede bẹẹ lasiko ipade r pẹlu awọn Kọmisọna ọlọpaa lawọn ipinlẹ gbogbo nilẹ yii nilu Abuja, tun salaye pe abẹ awọn Kọmisọna ọlọpa lawọn ipinlẹ ni ikọ SARS yoo maa wa bayii.

O fikun pe ikọ SARs to wa labẹ́ ijọba apapọ̀ ni igbakeji ọga agba ọlọpaa ati ẹka to wa fun isẹ iwadi ati ọtẹlẹmuyẹ yoo maa dari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Atiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà

O fikun pe awọn iwe ilana isọwọsisẹ to de ikọ to n gbogun ti iwa idigunjale naa, ni yoo jade laipẹ.

Adele ọga agba naa wa kede agbekalẹ ikọ oluwadi kan feto idibo, ti yoo wa fun iwadi ati igbẹjọ awọn to ba sẹ si ofin eto idibo.