2019 Elections: Ẹ̀mí èèyàn àti ilé ìjọba ń bẹ nínú ewu lásìkò ìbò 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Amẹrika sọ ẹgbẹ agbsumọmi ISIS ati Boko Haram n gbero lati da idibo gbogbogbo ọdun 2019 ru.
Bakan naa ni ijọba ilẹ Amẹrika kilọ fun awọn ọmọ orilẹede naa to wa ni Naijiria wi pe, oju lalakan fi sọri.
Ijọba Amẹrika fọrọ naa lede loju opo ayelujara rẹ, nibi ti o ti sọ pe ISIS ati Boko haram n gbero lati ṣọṣẹ laarin awọn eeyan ati ile iṣẹ ijọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Olu ile iṣẹ ilẹ Amẹrika ni Naijiria ni, ko daju boya awọn ẹgbẹ agbesumọmi naa yoo ṣe ikolu si olu ile isẹ Amẹrika, ṣugbọn o ṣe ikilọ fun awọn ọmọ orilẹede naa lati maa kiyesara ni gbogbo igba.
Bakan naa, olu ile iṣẹ Amẹrika rọ awọn ọmọ ilẹ naa lati yago fun ipejọpọ ti ero ba ti pọ, bẹẹ ni ki wọn jinna si ibi ti wọn awọn eeyan ba ti n fi ẹhonu han.
Koda ile iṣẹ naa tun rọ awọn ọmọ Amẹrika lati kiyesara nigba ti wọn ba wa ni ile iwe, ile iwosan, ibudokọ tabi ile ijọsin papa.
Bẹẹ ba gbagbe, idibo aarẹ ati ile aṣofin agba l'Abuja ni yoo kọkọ waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Keji ọdun 2019, ki idibo gomina to tẹlee lọjọ Keji oṣu Kẹta.









