Dino Melaye: Ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko ló lò láhàámọ́

Sẹnẹtọ Dino Melaye
Àkọlé àwòrán, Sẹnẹtọ Dino Melaye

Ile ẹjọ giga kan to wa nilu Abuja ti gba oniduro sẹnatọ to n ṣoju ẹkùn Iwọ Oòrun ipinlẹ Kogi, Dino Melaye.

Adajọ Yusuf Halilu gba ẹbẹ agbẹjọro rẹ, Mike Ozekhome, wọle ninu idajọ kan to gbekalẹ lọjọ Ẹti.

Adajọ ni ki wọ̀n gba oniduro Melaye nitori ailera rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Moses Melaye: Dino Melaye sùn ìta gbangba mọ́jú níléesẹ́ DSS

Amọ ṣa, Adajọ naa ni Melaye gbọdọ mu oniduro mẹta wa sile ẹjọ, ki igbesẹ naa to o le fidimulẹ.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kinini ọdun 2018 ni Melaye jọwọ ara rẹ fun awọn agbofinro, lẹyin bi ọsẹ kan ti wọn ti yi ile rẹ, to wa niluu Abuja,po.

Wọn fi ẹsun kan Dino pe, o lọwọ si bi awọ̀n kan ṣe yinbọn mọ ọlọpaa kan lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje ọdun 2018.