Lai Mohammed: Ọwọ́ Atiku kò mọ́ lórí ₦156m owó báńkì PHB tó wọmi

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Atiku Abubakar

Ijọba apapọ Naijiria ti kede pe, ni kete ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ba ti irinajo to se lọ si Amerika de, ni yoo wa wi tẹnu rẹ nipa ẹsun ajẹbanu kan ti wọn fi kan.

Minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed, lo fi ọrọ yi sita nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba labuja.

Mohammed sọ pe ko si anfaani kankan ti irinajo Atiku lọ si Amerika yoo mu ba ilẹ Naijiria.

''Ko yẹ ki a ma ran Atiku leti wi pe, kii ṣe Amerika ni wọn yoo ti dibo fun ati wi pe ti o ba pada de, o ni ẹjọ ti yoo jẹ''

Lai Mohammed ni, awọn ni ẹri tuntun lọwọ nipa owo ti Atiku gba bii owo ajẹbanu, eyi to ṣokunfa bi ile ifowopamo PHB ṣe wọlẹ

Àkọlé fídíò, Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

''Ẹri to wa ni ọwọ wa fi han wi pe, miliọnu mẹ́rìndínlọgọ́jọ naira ni Atiku Abubakar gba ninu owo yi ''

O tẹsiwaju pe, koda ki Atiku gba iwe igbele Amerika, Green card, iyẹn ko ni ko ma fidi rẹmi ninu idibo to n bọ lọna.

Bi a ko ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu APC ti n ti Atiku lọpọnpọn tẹlẹ, pe ko lọ si Amerika bo ba to bẹẹ.

Atiku ati awọn oyinbo ni Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Twitter

Idi ti wọn fi sọ bẹẹ ni pe, awọn kan ni Atiku lẹjọ lati jẹ ni Amerika ati wi pe, bi o ba fi le lọ si ibẹ, awọn agbofinro yoo mu.

Amọ ni bayi ti Atiku ti lọ si Amerika, iriwisi orisirisi lo ti n tele irinajo rẹ, ti esi Lai Mohammed si jẹ akọkọ ti alaṣẹ kankan labẹ ijọba to wa lode fi sita nipa iṣẹlẹ naa.