Lai Muhammed: Ó dìgbà tí a bá rí ìwé ìdájọ́ kí a tó sọ̀rọ̀

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileẹjọ giga apapọ nilu Oṣogbo gbe idajọ kalẹ pe ki awọn aṣofin apapọ o bẹrẹ igbesẹ lati yọ aarẹ loye

Ijọba apapọ ti fesi lori idajọ ileẹjọ giga apapọ kan loni eleyi to paṣẹ pe ki awọn aṣofin apapọ bẹrẹ igbesẹ irọloye lori aarẹ Muhammadu Buhari.

Minisita feto iroyin, Alhaji Lai Muhammed ni ileeṣẹ aarẹ ko tii tẹwọ gba iwe idajọ naa ati pe iroyin ọhun ṣajeji si ijọba apapọ.

Mohammed fesi ọrọ yii lasiko to fi n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade apapọ ọlọsọọsẹ igbimọ iṣakoso orilẹede Naijiria to waye ni ilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

" Mo ṣẹṣẹ n gbọ iroyin yii ni, o si di igba ti iwe idajọ naa ba tẹ wa lọwọ ki a to lee ṣe ohun kohun lorii rẹ."

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni owurọ Ọjọọru ni ileẹjọ giga apapọ kan nilu Oṣogbo gbe idajọ kalẹ pe ki awọn aṣofin apapọ o bẹrẹ igbesẹ lati yọ aarẹ loye pẹlu bi amofin Kanmi Ajibọla ati ajafẹtọ araalu kan, Sulaiman Adeniyi ṣe pe ẹjọ pe ki ileẹjọ kan an nipa fun awọn aṣofin apapọ lati rọ Buhari loye lori ẹsun aini iwe ẹri ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu.