Nigeria Elections 2019: Ezekwesili ti jẹ́ mínísítà ní Nàìjíríà lẹ́ẹ̀ mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ti a ba n darukọ àwọn eekan obinrin lorilẹede Nàìjíríà, a o le tii ka mẹta ka to darukọ Ọmọwe Obiageli Ezekwesili to n dupo aarẹ Naijiria.
Ilumọọka ni Ọmọwe Ezekwesili, ẹni ti o ti di oniruuru ipo mu ni Naijiria ati agbaye .
Yatọ si pe o jẹ ọkan pataki lara oludasilẹ ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan #BBOG to n ja fun ominira awọn ọmọbinrin to wa ni ahamọ ikọ Boko Haram, Ezekwesili jẹ ọkan lara awọn ọmọ Naijiria to n fi ojoojumọ ke tantan lori eto iṣakoso orilẹede naa.
Ipinlẹ Anambra la ti bi Oby, ni ọjọ́ kejidinlọgbọn, osu igbe ọdun 1963. O si kẹkọọ gboye gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ iṣiro owo.
Igba meji ọtoọtọ lo ti ṣe minista ni Naijiria, to si tun ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ Banki agbaye, ẹka ilẹ adulawọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita Ohun Alumọni láàrin ọdun 2005 si 2006
Ni ọdun 2005 ni Aarẹ Olusegun Obasanjo yan Ọmoọwe Ezekwesili gẹgẹ bi minisita ohun alumọni inu ilẹ, lẹyin to ti jẹ adari ẹka to n ri si amojuto eto isuna , nibi to ti gba inagijẹ 'Mama Due Process'.
Gẹgẹ bi minisita ohun alumọni, o ṣe agbatẹru abadofin to ni ṣe pẹlu alumọni ati iwakusa 'Minerals and Mining Act', idasilẹ ileeṣe iwakusa orilẹede Naijiria, o si tun rii daju pe ẹka naa rọrun lati wọ fun awọn aladaani.
Minisita Eto Ẹkọláàrin ọdun 2006 si 2007
Ipo minista ohun alumọni inu ilẹ, ni ọmọwe Ezekwesili wa, ti aarẹ nigba naa, Oloye Obasanjo tun ti sọ ọ di minista eto ẹkọ labẹ iṣakoso rẹ̀.
Gẹgẹ bi minisita eto ẹkọ, Ezekwesili ṣe atunto ẹka etò ẹkọ orilẹede Naijiria. Oun lo tun ṣe agbatẹru ibaṣepọ laarin ijọba ati aladaani fun eto ẹkọ to yanranti.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbakeji-aarẹ Banki Agbaye laarin 2007 si 2012
Ni ọdun 2007 ni arabinrin Ezekwesili di igbakeji aarẹ Banki agbaye, ni kete to fi ipo minisita eto ẹkọ silẹ ni Naijiria, ipo to dimu di ọdun 2012.
Gẹgẹ bi igbakeji-aarẹ Banki agbaye ẹka ilẹ Adulawọ yii, oun lo jẹ alamojuto gbogbo ohun to n lọ kaakiri awọn orilẹede mejidinlaadọta to wa ni 'Sub Saharan Afirika', o si tun jẹ adari owoyaa to le ni ogoji biliọnu dọla.

Oríṣun àwòrán, @obyezeks
Abẹ ẹgbẹ oṣelu ACPN ni o ti n dije sipo aarẹ orilẹede Naijiria
Ọmọwe Ezekwesili kede ipinnu rẹ lati dupo aarẹ orilẹede Niajiria ninu ọdun 2018 pẹlu alaye pe awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji to ti ṣe ijọba ri jẹ ọbayejẹ, ti ko si yẹ ki wọn wa ni ijọba mọ lorilẹede eyi.
Ọgbẹni Ganiyu Galadima ni wọn yoo jọ maa dije gẹgẹ bi igbakeji.
#BBCNigeria2019












