2019 Elections: Buhari ní wàhálà ìpolongo ìbò ló ṣèdíwọ́ wíwá síbi ìjíròrò

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Ariwisi ọtọọtọ lo ti n tẹle aiyọju Aarẹ Buhari si ibi gbagede ijiroro oludije Aarẹ lọjọ abamẹta.
Bi awọn kan ti ṣe n bẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ lati mase yọju sibi ijiroro naa, lawọn miran n sọrọ si Atiku Abubakar, to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP to yọju sibi ijiroro naa sugbọn to kọ lati kopa.
Amọ ṣa, agbẹnusọ fun igbimọ ìpolongo ìdìbò Ààrẹ Buhari, Festus Keyamo, ti mu alaye wa lori idi ti Aarẹ Buhari ko fi yọju.
Ninu atejade kan to fi sita, Keyamo sọ pe wàhálà igbokegbodo ìpolongo ìdìbò ti Aarẹ n se lẹnu ọjọ mẹta yii, lo mu ko ma wa.
Bakannaa lo ni, laipẹ yii ni Aarẹ Buhari ti kopa ninu ipade itagbangba kan pẹlu igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo, nibi ti wọn ti yannana ohun ti wọn ti gbe ṣe.
O tẹsiwaju pe, Aarẹ́ Buhari pẹ de lati ibi ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe ati ipolongo to lọ ṣe nipinlẹ Niger lọjọ abamẹta.
Esi si ọrọ Atiku
Igbimọ ipolongo naa, ninu atẹjade to fi sita fesi si ọrọ ti oludije ipo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe, oun ko le jiroro lai si Aarẹ Buhari nibẹ.
Wọn ni igbesẹ Atiku ti ṣe afihan wi pe, ohun ati ẹgbẹ PDP kan fẹ fi idibo ọdun 2019 koju ija si Aarẹ Buhari ni.
''Ti wọn ko ba ti ri Buhari koju ija si ,ọrọ ofifo lo ku ti wọn a ma sọ nibi ipolongo''
Ààrẹ Buhari àti Atiku ní Oludije méjì tí kò kópa nínú ijiroro náà eléyìí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí n retí wọ́n.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:












