Marriage Secrets: Kò sí bí obìnrin ṣe ní ìfẹ́ ọkọ tó, kò gbọdọ̀ sọ àṣírí márùn-ún yìí fún ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbeyawo se pataki, to si se koko nitori inu ile al ti n ko ẹsọ rode.
Amọ lasiko yii, ọpọ igbeyawo lo n daru nitori awọn idi kan tabi omiran, paapaa awn ohun to nii se pẹlu asiri laarin lọkọ laya.
Lootọ ni ko gbọdọ si aṣiri tabi nkan ikọkọ laarin tọkọtaya, ṣugbọn, awọn nkankan wa ti obinrin ko gbọdọ sọ fun ọkọ rẹ, bo ti wu ki wọn fẹran ara wọn to.
- Àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ń dọdẹ àwọn obìnrin òde òní
- Èèmọ̀! Wo ọmọbìnrin ọdún méjìlá tó ṣè'gbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin méjì láàrin oṣù kan
- Iléẹjọ́ wọ́gilé ìgbeyàwó nílànà ẹ̀sìn Islam pé kò bófin mu
- Oríṣìí àrùn mẹ́jọ tó máa ń ṣáábà mú aláboyún rèé
- Iwa nabi tu igbeyawo ọgbọn ọdun ka
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ
- 'Onígbèsè ni ìyàwó mi, ó n fi ìbálòpọ̀ dùn mi, ó tún ma n lu àwọn ọmọ láì ṣẹ̀'
- Tẹgbọn-taburo se igbeyawo ni Anambra
- Wo ìgbéyàwó olówó iyebíye tí awakọ̀ Kabúkabú ti jẹ̀bùn ọkọ N3.4m
Yoruba sa ni bi eti ko ba gbọ̀, inu kii bajẹ, bẹẹ si ni ko jẹ ki eti ẹni di, ni kii jẹ ki inu ẹni dun amọ ta ba fẹ ki alaafia wa ninu idile, awọn isẹlẹ mẹnumọ kan gbọdọ wa, ti obinrin gbọdọ fi pamọ.
Marun-un lara awọn nkan naa niyii:
1. Iye ọkunrin ti obinrin ti ba ni ibalopọ ko to pade ọkọ rẹ
Dandan kọ ni ki ọrẹkunrin tabi ọkọ ile rẹ mọ iye ọkunrin to ti ba ọ ni ibalopọ.
Idi ni pe o le ma a ro pe o le ṣe aṣiṣe pẹlu ọkunrin lọjọ iwaju. To ba wa a jẹ pe awọn ọkunrin naa pọ gan-an, ó le ro pe oniṣekuṣe tabi alagbere ni ọ.
Nitori naa, to ba beere lọwọ rẹ pe ọkunrin melo lo ti ba ọ ni ibalopọ, o le rẹrin, ko da lohun pe "wo o, jẹ ka gboju kuro nibẹ jare, ṣugbọn iye ti wọn jẹ ko ni nkan ṣe e pẹlu irinajo ifẹ wa".
2. Aṣiri nipa ọrẹkunrin tabi ọkọ rẹ nigba kan
To ba beere awọn nkan nipa ọkunrin naa, sọ iwọnba diẹ fun nipa rẹ.
Ma ṣe sọ awọn nkan to le mu ki ọkọ rẹ lero pe oun ko koju osunwọn to, tabi jẹ eniyan yẹpẹrẹ.
Ma sọ fun nipa bi ọkunrin ti o ti fẹ ri ṣe lowo to, bo ṣe mọ ibalopọ ṣe to, ati bo ṣe tọju rẹ si, fun ọkọ rẹ tuntun.
3. Ma sọ fun ọkọ rẹ pe o n yó ifẹ fun ọrẹ tabi arakunrin rẹ
Gbogbo wa la mọ pe o ṣe e ṣe ki ọrẹ tabi arakunrin ọkọ tabi iyawo ẹni wu eeyan lati fẹ.
Amọ, o lewu lati sọ ero yii fun ọkọ rẹ. Idi ni pe ọkọ naa yoo bẹrẹ si ni fura si iwa ati iṣe rẹ si ọkunrin ọhun, eyi to si le da ile yin ru.
Koda, o le ba ibaṣepọ rẹ pẹlu iru ọrẹ bẹẹ tabi arakunrin naa jẹ. Ni ero ọkọ rẹ, oun nikan ni ọkunrin to rẹwa ju.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo obìnrin tó ní ojú ara méjì, ilé ọmọ méjì àti ẹsẹ̀ mẹ́rin
- Gómìnà mẹ́ta láti Òkè Ọya ń dírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ àgbà Yorùbá fún Buhari
- Ìdí tí mo fi ń gbẹjọ́ rò fún Baba Ijesha - Amofin Ogala
- Háà! Ẹ wò ó bí ayé ṣe le mọ́ wa ní Afghanistan - Aráàlú figbe ta
- Mo bú sẹ́kún nígbà tí mo gba owó oṣù gelemọ àkọ́kọ́ ní Saudi-Arabia - Dokita
- "Ìbínú aráàlú ń bọ̀ lọ́dọ̀ gómìnà tó bá gbé ilẹ̀ wa sílẹ̀ fétò ìdaranjẹ̀"
- Èèkàn amúlúdùn méjì jáde láyé láàrín ọjọ́ méjì síra wọn
- Obìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ lé ní 60 dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó jì ẹ̀ṣọ́ ara òkú
- Ìmáàmù àgbà orílẹ̀èdè Ghana gbé owó kalẹ̀ fún kíkọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
4. Ma gbiyanju lati sọ fun pe o korira iya tabi ẹbi rẹ
Ko si bo ṣe wu ki iya ọkọ rẹ buru to, ma ṣe sọ fun ọkọ rẹ pe o korira iya rẹ.
Bakan naa ni awọn ẹbi rẹ. Ko si bi ọrọ naa ṣe le dun ọ to, mase gbiyanju lati sọ ọrọ buruku nipa wọn, tabi ri wọn fin ni oju ọkọ rẹ.
Ti o ba ni ede aiyede pẹlu ẹnikẹni ninu ẹbi ọkọ rẹ, fi ara balẹ ṣalaye fun, pẹlu ireti pe yoo ni òye idi ti o ko fi gba ti wọn.
Ọkọ rẹ yoo tun le ran ọ lọwọ lati yanju wahala naa.
Yoo si tun dena wahala miran to le fẹ ẹ bẹrẹ nipaṣẹ nkan ti o ba sọ nipa wọn.
5 . Mase fi ikọsilẹ halẹ mọ ọkọ rẹ
Ọjọ ti o ba ti fi ikọsilẹ halẹ mọ ọkọ rẹ, lasiko ti ede aiyede n waye laarin yin, lo ti fi ipilẹ nkan ti ko dara le lẹ fun igbeyawo yin.
Igbeyawo naa yoo bẹrẹ si ni iriri aigba ara ẹni gbọ, aibalẹ ọkan ati ifura.
Fifi ikọsilẹ halẹ ninu igbeyawo tumọ si pe o ko ni ẹmi igbagbọ ninu igbeyawo naa, ati pe ọwọ yẹpẹrẹ lo fi mu.
Ayaafi to ba jẹ pe iwa ipá tabi awọn ẹṣẹ miran to l'agbara ba n waye.
Gbiyanju pe ki ẹ jọ fọwọsowọpọ yanju awọn ipenija ti ẹ ba ni.

















