Divorce because of debt: 'Onígbèsè ni ìyàwó mi, ó n fi ìbálòpọ̀ dùn mi, ó tún ma n lu àwọn ọmọ láì ṣẹ̀'

oruka

Oríṣun àwòrán, others

Ọkùnrin kan, Emmanuel Bello ti bẹ ile ẹjọ ibilẹ kan to wa ni agbegbe Agege, nipinlẹ Eko, lati tu igbeyawo ka laarin oun ati iyawo rẹ, Motunrayo, nitori pe ko tọju oun to si tun n dunkooko mọ ẹ̀mí oun.

Ọkùnrin naa to jẹ baba ọlọmọ mẹrin, oṣiṣẹ ijọba, lo n gbe ni adugbo Acme Road, Ogba, tun fi ẹsun iwa agídí, fifi ọwọ lile tọ́ awọn ọmọ, ati awọn ẹsun mii kan iyawo rẹ.

Ọgbẹni Bello sọ nile ẹjọ pe iyawo rẹ "ni agídí, ko ni ibọwọ fun ni, to si tun jẹ ẹlẹrẹkẹ eebu".

Ko tan sibẹ o, o tun sọ pe onigbese ni iyawo oun jẹ́.

O ni "ọpọlọpọ igba lo sa kuro nile ni owurọ kùtùkùtù, nitori awọn to jẹ ni gbese.

"Kii ṣe iyawo gidi, bẹẹni kii ṣe iya to dara."

Bello sọ pe itiju naa pọ debi i pe oun san miliọnu kan aabọ Naira fun diẹ lara awọn to jẹ lowo.

"Nigba ti sakiyesi pe iyawo mi ti n ṣi iwa hu, ti ko si tọju awọn ọmọ wa, mo fi ẹjọ sun àwọn ẹbí rẹ, sugbọn ko si ayipada kankan.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

" Iyawo mi n ri mi fin, ko tun gba ki n ba ni ibalopọ mọ.

"Nise lo maa n wọ awọtẹlẹ ati ṣòkòtò penpe sun, ki n ma ba le ba ni ibalopọ."

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Ọgbẹni Bello ṣalaye pe oun kọkọ ni ireti pe yoo yí padà, àmọ́ o tun n buru si ni.

"Pabanbari ni pe o wa fẹ́ràn ode ariya gan-an."

O ni oun gba sọọbu fun obinrin naa lati ma a fi ta ọjà, sugbọn ko da si bukaata inu ile ri.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

O tun ni: "Ọpọlọpọ ọjọ lo sa kuro nile ni aago marun-un owurọ, ki awọn to jẹ lowo lai sọ fun mi, ma ba a ba nile . Mo pada san miliọnu kan aabọ Naira lara gbese naa.

"Nise lo tun ma n lu awọn ọmọ lai ṣẹ ẹ̀sẹ̀ kankan.

" Ẹru n ba mi lati ma a ba gbe,nitori pe o ti leri lati fi iya jẹ mi."

Àkọlé fídíò, Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol

Ọgbẹni Bello sọ pe dandan ni ki ile ẹjọ tu igbeyawo ọdun mọkandinlogun naa ka, nitori pe oun ko le fi ara da awọn iwa buruku Motunrayo mọ.

Bakan naa lo fẹ ki ile ẹjọ yọnda àwọn ọmọ wọn fun oun.

Àmọ́ nigba ti iyawo n ṣorọ, o ni irọ ni pe ọkọ oun ní lara owo okoowo oun, ati pe oun kii tọju rẹ ati awọn ọmọ.

"Mo ṣi nifẹ ọkọ mi, mi o si fẹ ẹ kọ silẹ."

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Motunrayo to jẹ abaniransọ bẹ ile ẹjọ pe ko ma a tu igbeyawo naa ka.

Oun naa fi ẹsun kan ọkọ rẹ pe kii gbọ ọrọ ẹnu oun tabi imọran ti oun ba fun.

O ṣalaye pe ki awọn ọmọ ma ba ya iyakuya ni oun ṣe n ba wọn wi.

Adajọ ile ẹjọ naa, Ọgbẹni Biola Alani sọ fun tọkọtaya naa lati wa ni alaafia, o si sun igbẹjọ wọn si ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ fun idajọ.