Winners Pastors Sack: Oyedepo tún ti fèsì sí áwọn tó bẹnu atẹ́ lu ìgbésẹ̀ to gbé lórí àwọn Pásítọ̀ rẹ̀

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, davidoyedepomin

Bisọọbu ijọ Winner tun ri fesi lati da awọn to n sọrọ alufansa sii nitori pe o le awọn pasitọ ijọ rẹ lẹnu isẹ nitori pe wọn ko so eso.

Bakan naa lo Soko ọrọ ranṣẹ si awọn to tako lori ile ijosin onijoko eniyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun ti o pe ni "The Ark"

Oyedepo ni awọn olusọaguntan ti oun le n saisan bakan naa wọn ko so eso rere, gẹgẹ bi gbedeke ti oun fun wọn lati jere o kere ju emi mejila lọsẹ.

O ni: Awọn ijọ igberiko n lọ lọwọ ti awọn nkọ idamẹwaa ati ọrẹ ti wọn n da nibẹ ti wọn ba ko jọ ni ogoji ọdun ko le kọ iru ile ijọsin ti ijọ n kọ fun wọn.

Mo gbọ pe awọn kan n sọ pe nitori awọn ni owo ọrẹ ni oun se ni ki wọn maa lọ".

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, davidoyedepomin

" Nitori pe ẹ saisan. Ẹ o so eso. A fayin tu.

"A ran yin lọ si igberiko ki ẹ lọ gba ọkan eniyan mejila la lọsẹ ki ẹ si ri daju pe eniyan mẹfa ninu wọn wa si ile ijọsin, sugbọn lẹyin osu mẹfa ko si eniyan mewaa ni sọọsi. E o so eso, amoju gidi lo gbe wa de ibi ti a wa yii

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

"Ti eniyan ba fi ọmọsẹ ti ko so eso kalẹ, o tumọ si pe eni naa kii se adari rere'.

Ẹ ni ẹtọ lati kowe fipo silẹ, a ní ẹtọ lati da yin duro lẹ́nu iṣẹ. Bi o se ri ni ibi gbogbo niyẹn.

"Wọn n kọ ile alaga ẹgbẹrun lọna ọgọrun. Ṣe wọn gba owo lọwọ yin ni?

O yẹ ki wọn di owo naa kọ ile ìṣe, ṣe ẹyin ni ẹ o maa se eto isuna owo olowo ni. Ẹ gbe enu yin dakẹ ki ẹ si kọju mọ iṣẹ yin.

Wọn fẹran lati maa gbọ lati ọdọ mi, mo si feran lati maa gbọ lati ọdọ mi, emi naa si feran lati maa dawọn lohun"

Àkọlé fídíò, Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò