Banditry in Nigeria: Àwọn olùjọ́sìn náà ń gbaradì fún ìsìn ọjọ́ ìsinmi ní àwọn ajínigbé ya bò wọ́n

aworan an agben kan

Oríṣun àwòrán, other

Awọn gende agbebọn kan ti kọlu ijọ Living Faith, tii se ara ijọ David Oyedepo eyi to wa nilu Osara loju ọna Lokoja si Okene nipinlẹ Kogi.

Awọn agbebọn naa lo ya wọ ọgba ile ijọsin ọhun lasiko tawọn akọrin atawọn ojisẹ Ọlọrun miran n gbaradi fun isin ọjọ isinmi lopin ọsẹ to kọja.

Ka to sẹju pẹ, o kere tan, wọn ti ji mẹta gbe lọ lara awọn ọmọ ijọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni se ni awọn ajinigbe ọhun n yinbọn laibikita lati le awọn eeyan to fẹ koju wọn sẹyin, ti wọn si raye gbe awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ti wi, Alaga ijọba ibilẹ Adavi nibi ti isẹlẹ naa ti waye, Joseph Omuya Salami lo fidi isẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Aje lati ẹnu akọwe feto iroyin rẹ, Habeeb Jamiu.

Koda, Salami ni oun ati ọga ọlọpa to wa lẹkun naa ni awọn dijọ se abẹwo sile ijọsin naa, nibi ti wọn ti ji awọn eeyan lọ.

O wa fi ọwọ idaniloju sọya pe aayan ti n lọ pẹlu awọn agbofinro lagbegbe naa lati ri daju pe wọn doola awọn eeyan naa lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Amin iyasọtọ kan

Ọjà títà, ọ̀kadà gígùn àti epo títà dèèwọ̀ ní Zamfara torí ọṣẹ́ ajínigbé, agbébọn

aworan an agben kan

Oríṣun àwòrán, other

Gulegule awọn agbebọn ni ipinlẹ Zamfara, lapa iwọ orun ariwa orilẹede Naijiria ti sọ awọn iṣẹ ọrọ aje kan di eewọ bayii.

Awọn ọrọ aje bii nina ọja ọlọsọọsẹ, ọkada gigun lati alẹ wọ idaji pẹlu fifi ọkọ kiko awọn ẹran ọsin jade kuro ni ipinlẹ naa lo ti di eewọ bayii,

Bẹẹ ni ẹnikẹni to ba fẹ ko ẹran ọsin wọ ipinlẹ naa gbọdọ gba aṣẹ lẹyin iwadii finni-finni lati mọ otitọ iru ẹranko ti wọn fẹ ko wọle.

Eyi ni diẹ lara awọn igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Zamfara n gbe lati dena gbọnmọgbọnmọ iwa ijinigbe, ipaniyan ati jiji ohun ọsin ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọja ọlọsọọsẹ saba maa n waye lawọn agbegbe igberiko nipinlẹ naa nibiti awọn eeyan kaakiri ileto ti maa n peju si gbangba lọsọọsẹ lati ṣeto karakata bii ohun jijẹ, ohun ọsin, awọn ohun elo oko ati aṣọ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Bakan naa ni awọn alaṣẹ ipinlẹ naa tun ti gbe gbogbo ileepo nipinlẹ naa tipa ayafi awọn ileepo to wa ni ilu Gusau to jẹ olu ilu ipinlẹ naa, atawọn olu ilu ijọba ipinlẹ mẹrinla to wa nibẹ

Bakan naa ni wọn paṣẹ fun awọn ileepo ti wọn yoo wa ni ṣiṣi naa pe wọn ko gbọdọ ta epo ti owo rẹ ju ẹgbẹrun mẹwa naira fun ẹnikẹni.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Zamfara, Eyuba Elkanah ṣalaye fun awọn akọroyin lolu ilu ipinlẹ naa pe aṣẹ ti jade fawọn agbofinro nipinlẹ naa lati ṣiṣẹ lori awọn ofin tuntun ti ijọba gbe kalẹ wọnyii.

Orilẹede Naijiria n ba ipenija ipaniyan, ijinigbe pawo lọwọ awọn agbebọn atawọn ipinija ọrọ abo miran finra lọwọ bayii eleyii to mu ki ijọba, awọn ilu gbogbo atawọn idile kọọkan ni ipinlẹ naa o gbe awọn igbesẹ to nira diẹ lati koju iṣoro naa.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria