NDA Invasion: Fr Mbaka ní bí Buhari kò bá yíwà padà, díẹ̀ ní ìṣẹ̀lẹ̀ Afghanistan yóò jẹ́

Fr Ejike Mbaka ati aa Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, State House Abuja

Alufa ijọ Adoration Ministry Enugu Nigeria, AMEN, Ẹniọwọ Ejike Mbaka ti ọpọlọpọ mọ si Fada Mbaka sọrọ lori ikọlu to waye si ileẹkọṣẹ agba fawọn ọmọogun ni Naijiria, NDA.

Ojisẹ Ọlọrun naa wa sapejuwe ikọlu ọhun bii ibẹrẹ pẹpẹ awọn ohun ajalu to n bọ lọna fun orilẹede Naijiria.

O ni bi aarẹ Buhari ko ba tete yi ọna rẹ pada tabi ki Ọlọrun tubọ dasi ọrọ Naijiria, nkan yoo yan lorilẹede Naijiria, koda kekere ni ikọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fada Mbaka to sọrọ yii lasiko isin ni ileejọsin naa, tun ṣekilọ pe bi awọn adari ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ fun atunṣe, bintin ni ohun to ṣẹlẹ lorilẹede Afghanistan yoo jẹ lẹgbẹ eti ti yoo ṣẹlẹ si NAijiria lọjọ iwaju.

Iranṣẹ Ọlọrun naa tun pe fun itusilẹ awọn eekan aṣiwaju ẹgbẹ ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu kuro ninu ahamọ.

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́

O fi kun un pe o han gbangba pe iṣoro to n koju Naijiria kọja ọrọ Nnamdi Kanu, ati pe awọn to kọlu ile ẹkọṣẹ agba fawọn ologun naa kii saa n ṣe Kanu.

"Gẹgẹ bi mo ṣe sọ fun yin loṣu meji sẹyin, pe ohun ti ẹ n ri bayii ibẹrẹ wahala to n bọ ni, ojulowo wahala ṣi n bọ lọna.

Ifaara lasan leyi ti wọn n kọlu ileẹkọṣẹ agba fawọn ọmọogun ni Naijiria, NDA yii, apa keji n bọ"