Laide Bakare and Kemi Afolabi: Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrin Laide Bakare àti Kemi Afolabi nítorí ọkunrìn?

Laide Bakare, Kemi Afolabi ati Dauda Sulaimon (Gida)

Oríṣun àwòrán, laide bakare/others

Àkọlé àwòrán, Laide Bakare, Kemi Afolabi ati Dauda Sulaimon (Gida)

Yoruba ni, ti owe ba jọ owe ẹni, ta o ba le f'esi, a jẹ pe ẹru ija lo n ba onitọhun.

Lo difa fun gbajugbaja, apọnbeporẹ, arẹwa oṣerebinrin meji, Laide Bakare ati Kemi Afolabi, to jọ n pa owe eebu lori ayelujara Instagram wọn.

Botilẹ jẹ pe awọn mejeeji ko darukọ ẹni ti wọn n pa owe mọ, iroyin to n lọ labẹlẹ ni pe aarin ọrẹ mejeeji ti daru.

Kemi Afolabi ati Laide Bakare jẹ ọkan lara awọn ọrẹ timọtimọ to wa ni agbo awọn oṣere tiata Yoruba.

Awọn mejeeji fẹran lati ma a wọ anko aṣọ, wọn jọ ma n lọ si ode ariya ni, ko da o fẹ ẹ ma si nkan ti wọn kii ṣe papọ.

Bakan naa ni wọn ti yan orukọ ti kan 'my twinee' ti wọn n pe ara wọn, ni gbogbo igba ti wọn ba n fi ifẹ han si ara wọn lori ayelujara.

Orukọ naa tumọ si 'ẹnikeji mi', 'ibeji mi'.

Eyi si jẹ pataki nkan to jẹ ki ọpọ eeyan o ma a fura pe aarin wọn ti daru. Nitori pe ninu òkò ọrọ ti awọn mejeeji kọ sori Instagram ni ọjọ diẹ sẹyin, 'twinnie' wọpọ ninu wọn.

Oko ọrọ ti Kemi Afolabi ati Laide Bakare sọ lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, Instagram/Gistlovers_blog1

Àkọlé àwòrán, Oko ọrọ ti Kemi Afolabi ati Laide Bakare sọ lori ayelujara

Ninu ọrọ ti Kemi kọ ni tiẹ ni ede Gẹẹsi, ṣugbọn ti a o tumọ si Yoruba, o ni "Kẹmo, ọmọ to rẹwa, eeyan kan to jẹ alarun ọpọlọ, to n wa ki awọn eeyan wo ibi ti oun wa sọ pe oun lo sọ mi di irawọ oṣere.

Were alaṣọ... Ta lo ni Twinnie isọnu. Yinmu. Ṣe Kemi alagbara wa kere ni?... Awọn da? Wọn o to bẹ ẹ."

Kini Laide Bakare sọ?

Nigba ti Laide Bakare naa yoo kọ ọrọ tiẹ naa lori Instagram bakan naa, abẹ fidio kan to ṣe pẹlu oṣerekunrin kan ti wọn jọ n jo, lo kọ ọrọ naa si. Ede Gẹẹsi lo n naa kọ ọ.

Ikede Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, laide bakare

O ni "...awọn da? Wọn o to bẹẹ. Ko si nkan ti awọn oni ikorira le sọ tabi ṣe. Ko le dun mi rara. Abi eleyi fẹ ẹ tẹ ni? Taa ni ẹ? Baba nla ìyá rẹ ni Laide Bakare. Mo tobi ju awọn nkan radarada kan lọ, omidan were. Taa ni Twittie rẹ? Alaye bajẹ. Iwọ to o da bi ọkunrin!!!!".

Lẹyin gbogbo ọrọ ti wọn kọ yii, ni oniroyin ari ayelujara Gistlover gbe sita pe ọrọ ọkunrin lo n fa ija laarin ọrẹ meji naa.

O ni akẹẹgbẹ wọn lọkunrin, Dauda Sulaimon ti ọpọ mọ si Gida, ni awọn mejeeji n ja si. Iroyin ti gbe e ri pe ọrẹkunrin Kemi Afolabi ni osẹrekunrin naa, botilẹ jẹ pe o ni iyawo nile.

Ṣe lootọ ni wọn n ja si Gida?

Lootọ ni a ko ti i le fidirẹ mulẹ pe ọrọ ọkunrin lo gé okùn ọrẹ laarinKemi Afolabi ati Laide Bakare.

Ṣugbọn ni owurọ ọjọ Aiku, ni Bakare fi ikede kan sita lori ẹsun naa.

Ninu ikede naa to fi si ori Instagram rẹ, pẹlu aworan oun ati Kemi, ati ti ọkunrin ti iroyin sọ pe wọn n ja si, lo ti sọ pe o sẹ koko fun oun lati sọrọ lori ẹsun naa, nitori bi awsn eeyan ṣe n pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ, ati pẹlu atẹjiṣẹ lati igba ti iroyin naa ti jade.

O ṣapejuwe iroyin naa gẹgẹ bi ọrọ to pani lẹẹrin.

O ni "Ẹ jẹ ko ye wa daadaa pe Laide Bakare ko ni i wọ ara rẹ nilẹ debi i pe ko ma ja nitori ọkunrin lagbo iṣẹ wa.

Atẹjade Laide Bakare lori ẹsun naa

Oríṣun àwòrán, laide bakare

Abala keji ikede ti Laide Bakare fi sita lori ẹsun pe ọrọ ọkunrin lo da aarin oun ati Kemi Afolabi ru

Oríṣun àwòrán, laide bakare

Àkọlé àwòrán, Abala keji ikede ti Laide Bakare fi sita lori ẹsun pe ọrọ ọkunrin lo da aarin oun ati Kemi Afolabi ru

Igba diẹ ti iṣẹ da wa pọ, ni mo foju ri akẹẹgbẹ mi lọkunrin ti wọn n sọ yii. Ẹ wadii ootọ daadaa. Ko le ṣẹlẹ lailai."

O ni ọrọ ti oun kọ laipẹ yii jẹ esi fun akẹẹgbẹ oun lobinrin to bu oun lori ayelujara, dipo ko pe oun lori foonu lati fi ẹhonu rẹ han.

"Gbogbo eeyan lo mọ mi pe tile-toko ni mo n ba a ṣe bi ẹni pe a ti mọ ara wa tipẹ. Gbogbo eeyan ni mo n fi ifẹ han si, lai dẹyẹ si ẹni kankan."

O sọ pe oun kii fi agba tabi ipo ọga han lori ẹnikẹni, koda to fi mọ awọn ti oun kọ niṣẹ.

O ni oun dupẹ lọwọ ẹbi ati awọn ololufẹ oun fun ipe ati awọn ọrọ ti wọn fi ranṣẹ si oun lori iroyin naa.