Àwọn ológun Israel pàṣẹ fún gbogbo olùgbé Gaza láti kúrò torí ìkọlù ńlá ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awifun ni ko too dani, agba ijakadi ni.
Bẹẹ lo jọ pe ọrọ ri bayii fun wọn ni Gaza ti ogun ti n waye, pẹlu bi ikọ ologun Isreali ṣe gbe ikilọ tuntun kalẹ fun wọn lati kuro niluu naa kia.
Oju opo X ni agbẹnusọ IDF lẹka ede Larubawa, Avichay Adraee, ti kilọ pe:
"Si gbogbo olugbe ati gbogbo eeyan to ba ṣi wa ni Gaza ati agbegbe rẹ, fun aabo yin, ẹ kuro nibẹ lẹsẹkẹsẹ."
Atẹjade naa fi kun un pe, "o lewu gidi bi ẹ ba ṣi n duro lagbegbe naa".
Itumọ eyi ni pe Israel n paṣẹ pe ki eeyan ti iye wọn to miliọnu kan, kuro ni agbegbe to tobi ju ni Gaza.
Wọn ni ki wọn kọri sibi ti wọn lo daa fun ọmọniyan, iyẹn jingun-jingun al-Mawasi, ni apa Guusu.
Israel loun yoo pese ounjẹ ati itọju ilera fun wọn nibẹ.
Ṣugbọn al-Mawasi ti wọn ni ki wọn lọ yii, ati awọn ibomiran ti wọn ni eeyan le gbe lo jẹ pe wọn ti ju ado oloro sibẹ leralera ri.
To bẹẹ ti ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) fi sọ pe ko sibi ti a le pe ni aabo tabi ibi isadi mọ ni Gaza.
Ṣaa, awọn kan ṣi n ni ireti to kere bii koro mostadi, pe boya idasi Aarẹ Donald Trump, tun ṣi le mu ki Israeli ati Hamas tun jọ sọ asọyepọ, ti wọn yoo si jẹ ki ogun pari.
Ṣugbọn ọwọja Israeli ni Gaza ati agbegbe rẹ ti lagbara pupọ, o si n le si I ni pẹlu, debii pe wọn n ju ado oloro si Gaza loru mọju.
Olootu ijọba Isreali, Benjamin Netanyahu, sọ pe o le ni aadọta ile ti awọn ologun Israeli ti sọ ado oloro si laaarin ọjọ meloo sẹyin.
O si ni eremọde lasan ṣi niyẹn, o ni wọn yoo ri ojulowo idan nigba ti awọn ba gbe ija nla wọ Gaza.
Israeli ni oun ti pinnu lati ṣẹgun Hamas ati ohun to ba jọ mọ ọn, oun yoo si lo gbogbo agbara lati ṣe eyi.
Ikilọ yii n waye lẹyin ti ikọ alaabo Israeli ṣepade loṣu to kọja, nibi ti wọn ti fẹnuko lati gba akoso agbegbe ti ẹgbẹẹgbẹrun awọn Palestine fi ṣebugbe.
Awọn agbegbe ti wọn tun ni ki wọn kuro ni Old City ati Tafah, titi de Ila Oorun ati ibi omi okun apa Iwọ Oorun.
Wọ́n tún fi ìwé kéde ìkìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Yatọ si ikede ori ayelujara ti Israeli fi kilọ fawọn eeyan lati fi Gaza silẹ, bẹẹ naa ni wọn tun kede ikilọ ọhun sinu iwe, ti wọn si n ju u silẹ kaakiri.
Irufẹ iwe naa ti ẹka iroyin Reuters ri, ṣafihan fidio bi wọn ṣe n ju iwe naa to n jabọ silẹ.
Awọn ohun ti wọn si fi ede Larubawa kọ sibẹ naa ni pe ' ẹ kuro kia''
Gaza, ìlú tí ìyàn ti ń mú, tí ìkọlù kò sinmi
Yatọ si ti ebi ọpapanla to n pa wọn ni Gaza lati igba pipẹ wa, lati bii ọsẹ meloo sẹyin ni ikọ ologun Israeli tun ti n kede pe oun yoo tun kọlu wọn.
Ikede ọhun n waye lẹyin ipade ati ikilọ Israeli, pe oun yoo gba Gaza poo!
Ilu Gaza yii, ti di ibi kan to jẹ bi ogun ṣe n lọ nibẹ to, awọn eeyan tun n sa lọ sibẹ lati bọ lọwọ ikọlu lapa ibomiran.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo jẹ pe abẹ atibaba ni wọn n gbe ni Gaza, nibi to jẹ oju ọja ilu naa ki adanwo yii too de.
Pupọ ninu awọn atibaba ọhun ni ko si mọ bayii, lati bii oṣu kan ti Isreali ti = ṣafikun ikọlu.
Iwadii BBC fidi eyi mulẹ.
Gaza yii kan naa ni ìyàn ti n mu to bẹẹ ti ọrọ fi kan ajọ Integrated Food Security Phase Classification (IPC) – ti ajọ UN n ṣagbatẹru rẹ.
Ẹka to n ri si bi ebi ṣe n pa wọn to ni Gaza, ṣalaye loṣu Kẹjọ, pe ebi aṣekupani lo n pa wọn ni Gaza.
Wọn ni o to idaji miliọnu eeyan to n koju agbako ebi naa nibẹ.
Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, awọn eeyan ko fẹ kuro nibẹ.
Ko si aaye nileewosan mọ fun itọju, ko si sibi ti wọn le fori si lati sun tabi maa gbe lọ.
Gbogbo ohun tí wọ́n lè fi yè ní Gaza ni Israel ń bàjẹ́ -Òṣìṣẹ́ UN

Oríṣun àwòrán, KHAMES ALREFI/ANADOLU VIA GETTY IMAGES
Ajith Sunghay, oṣiṣẹ kan lati UN, ọfiisi Kọmiṣanna fun ẹtọ ọmọniyan, High Commissioner for Human Rights (OHCHR), kilọ pe ikọlu ti Israeli n gbero rẹ yii yoo le gan-an.
"Ohun ti a ko ri ri la maa ri lọtẹ yii, gbogbo ohun to le da aabo bo araalu ni wọn n bajẹ."
Bẹẹ lo ṣalaye fun BBC Newsday.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ni yoo gbiyanju lati ṣi lọ si apa Guusu, sugbọn awọn kan naa wa ti wọn ko ni i fẹ lọ rara.
Wọn mọ pe bi wọn ba fi le kuro, wọn ko le pada si Gaza mọ.
Ajith lo ṣalaye bẹẹ.
Iroyin iṣẹlẹ Gaza n tẹsiwaju, a o maa mu wa bo ba ṣe n lọ.














