Agbébọn kọlu ibùdókọ̀ ní Jerusalem, ṣekúpa èèyàn mẹ́fà, mẹ́jọ farapa, lásìkò tí wọ́n ń lọ ibiṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan, eeyan mẹfa lo ti jade laye, nigba ti awọn mẹfa mii tun farapa yanayana lẹyin ti awọn agbebọn ọmọ Palestinian kan kọlu awọn eeyan ni Jerusalem.
Ileeṣẹ ọlọpaa Israel sọ pe "Awọn agbesunmọmi meji wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ" wọn si bẹrẹ si n ṣina ibọn fun ọkọ akero.
Amọ ṣa, ọmọ ogun kan ati araalu kan da ina ibọn mii pada fun awọn agbebọn naa ti wọn si gbẹmi wọn.
Ileeṣẹ adoola ẹmi Magen David Adom ni Israel sọ pe lọwọ yii, eeyan mẹjọ lo n gba itọju lọwọ lẹyin ti ibọn ba wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹgbẹ kankan to tii kede pe oun lo wa nidi ikọlu naa, ẹgbẹ Hamas ti kan sara si ikọku ọhun.
Nigba ti olootu ijọba, Benjamin Netanyahu ṣabẹwo sibi ikọlu naa, o ni oniruru ọna lawọn ọta Israel fi n gbogun ti orilẹede oun.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun Israel ni gbogbo agbegbe to yẹ lawọn n ṣọ loju mejeji lati ri daju pe awọn agbesunmọmi ko ṣe akọlu si awọn eeyan nibẹ.
Akọlu ọjọ Aje yii waye lasiko ti awọn eeyan n lọ si ibiṣẹ oojọ wọn ti ọpọ eeyan si n gbiyanju lati wọ ọkọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede naa, Lt Dean Elsdunne sọ pe awọn agbofinro ti ri awọn ohun ija ati ọbe to wa lara awọn agbesunmọmi ọhun.
O ni "A n ṣiṣẹ lati ṣe idanimọ ẹnikẹni ati gbogbo awọn to gbero, awọn to ṣatilẹyin fun ati gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu yii."
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle Israel jabọ pe igbagbọ wa pe awọn abule al-Qubeiba ati Qatanna ni Palestine lawọn to ṣe ikọlu naa ti wa.
Awọn aworan ara awọn ọlọpaa ṣafihan bi awọn eeyan, to fi mọ awọn ọmọde ṣe n sa asala fun ẹmi wọn lasiko ikọlu naa.
Ọkan lara awọn to farapa nibẹ, Ester Lugasi sọ pe "Lojiji ni mo gbọ ti iro ibọn n dun lakọlakọ… mo sare ẹmi mi fẹ ẹ bọ. Mo tilẹ ro pe ọjọ iku mi ti de ni."
Daniel Katzenstein, to jẹ oṣiṣẹ adoola ẹmi sọ fun BBC pe ẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ Mohammed wa lara to ran awọn lọwọ lati doola awọn ti ọrọ naa kan.
O ni "Mohammed ni orukọ rẹ' oun naa ran wa lọwọ lati gbe awọn eeyan.
"Eyii kii ṣe ija laarin Islam ati Judaism, o jẹ ija laarin awọn ti wọn fẹ ṣe ẹlomiran ni ibi atawọn ti wọn ko fẹ padanu ẹmi wọn."















