Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìpàdé NUPENG, Dangote àti ìjọba ṣe forí ṣánpọ́n, tí ìyanṣẹ́lódì àwọn awakọ̀ epo sì wọ ọjọ́ kejì

Ọkọ agbepo to lọwọọwọ ninu aworan yii, igi wa lẹba ọna mejeeji, bẹẹ ni ọkunrin kan n re kọja lọ nin aworan yii.

Oríṣun àwòrán, NURPHOTO VIA GETTY IMAGES

Àkọlé àwòrán, Aworan ọkọ agbepo lori ìla , pẹlu ọkunrin kan to n kọja lọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ojo to rọ ti o da ni ọrọ ileeṣẹ elepo NUPENG ati ijọba apapọ pẹlu ileeṣẹ elepo Dangote to n lọ lọwọ, Oluwa nikan lo mọ iye ẹni to le pa.

Idi ni pe bi ipade ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ Dangote pẹlu NUPENG ti wọn ṣe lalẹ ọjọ Aje ṣe pẹ to, ati bi ijọba apapọ ṣe da si i to, ko ti i si asọye kankan.

Awọn ibudo ti NUPENG n ja epo si tẹlẹ kaakiri orilẹede yii ni wọn tipa lọjọ Aje, ti wọn fi tako ẹsun pe ileeṣẹ ifopo Dangote sọ pe awọn oṣiṣẹ rẹ ko gbọdọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ awakọ epo.

Nibi ipade ti wọn fẹ fi yanju aawọ naa ni gbogbo igun to kan peju si, titi kan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC. Minisita fun ọrọ iṣẹ; Muhammed Dingyadi, wa lara awọn alaga ipade naa ti wọn kọkọ fi si aago mẹwaa aarọ.

Ipade ọhun ko bẹrẹ titi di aago marun-un irọlẹ kọja diẹ, nitori ai tete de awọn ti ọrọ kan.

Kí ló ṣẹlẹ̀ nibi ipade naa?

Gẹgẹ bi awọn kan lara awọn to wa nipade naa ṣe wi, lẹyin ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ, gbiyanju lati ri i pe awọn igun tọrọ kan fẹnuko, ki wọn si tọwọ bọwe adehun, wọn ka ohun to wa ninu iwe adehun naa si etigbọọ gbogbo wọn pata.

Ṣugbọn awọn aṣoju ileeṣẹ Dangote tako awọn kan ninu adehun naa, eyi lo si fa a ti wọn tun fi pẹ nidi ẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

Nigba ti yoo fi di aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹẹẹdogun lalẹ ọjọ Mọnde naa, awọn eeyan yii ṣi n sọrọ lori afẹnukosi.

Ṣugbọn ibi pẹlẹbẹ ni abẹbẹ ipade naa pada fi lelẹ bi ilẹṣe ṣu to ki wọn too pari rẹ.

Ẹ o ranti pe ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni awọn awakọ agbepo NUPENG ti leri lati da iṣẹ silẹ, ti wọn si mu ileri naa ṣẹ lọjọ Aje ana ti i ṣe ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii.

Bakan naa ni ijọba apapọ ti bẹ wọn ṣaaju pe ki wọn ma ṣe yanṣẹlodi , ṣugbọn wọn kọti ọgbọin si i ẹbẹ ijọba.

Àwọn ibi ti ìyanṣẹ́lódì náà ti ń foju hàn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn ibudo ti iyanṣẹlodi naa kan ni ibudo ifọpo Aradel to wa ni Obele, ni Port Harcourt, ati 'Kwale Hydrocarbon' to wa ni ipinlẹ Delta.

Awọn ibudo kan naa ti n tẹle igbesẹ yii niluu Eko, awọn dẹrẹba to n wa ọkọ epo gbe ọkọ wọn kalẹ si iwaju ibẹ lai gba epo ni.

Bẹẹ la ri lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn n fi ẹsun kan ileeṣẹ elepo Dangote ati MRS pe wọn fẹ gba iṣẹ mọ awọn lọwọ.

Awọn ileepo bii Aiteo, RainOil, Shell+, First Royal, ati MAO, Hensmor, One Terminals, Africa Terminals, Integrated Oil and Gas atawọn mi-in ni wọn ti ilẹkun wọn pa lọjọ Aje ana, awọn oṣiṣẹ ko si nibẹ rara.

Awọn mi-in ni A&E, Matrix, Parker AY Shafa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nipinlẹ Sokoto, awọn oṣiṣẹ NUPENG ti ti awọn ileepo kaakiri. Bẹẹ ni awọn aṣoju ẹgbẹ naa n tilẹkun awọn ti ko ba tẹle aṣẹ naa pa funra wọn.

Awọn o ṣoju mi koro sọ pe niṣe ni wọn ja ewe soju ọna ti wọn si ti awọn ibi kan pa nigboro, pẹlu bi wọn ṣe gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ loru mọju ana lati ọdọ awọn alaṣẹ wọn.

PENGASSAN ṣàtìlẹyìn fún NUPENG, kọ ẹ̀yìn sí Dangote

Ẹgbẹ elepo ti a mọ si Petroleum and Natural Gas Senior Staff Association of Nigeria( PENGASSAN ) ti kede atilẹyin wọn fun NUPENG bi ọrọ yii ṣe n lọ lọwọ.

PENGASSAN ni ko si idi kan fun awọn awakọ epo Dangote lati ma ṣe ẹgbẹ oṣiṣẹ awakọ epo.

Ninu atẹjade ti Akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Lumumba Okugbawa, fi sita lọjọ Aje ni wọn ti ni bi ko ba si ayipada nipa gbigba ẹtọ awọn awakọ ti Dangote n gba siṣẹ, awọn pẹlu yoo darapọ mọ iyanṣẹlodi naa.

Wọn ni latigba ti Dangote ti ṣi ileeṣẹ epo rẹ ni ko ti jẹ ki awọn awakọ rẹ darapọ mọ PENGASSAN ati NUPENG, gbogbo ipa lawọn si ti sa lati yi eyi pada ṣugbọn Dangote ko jẹ.

Bakan naa ni awọn ẹgbẹ bii Natural Oil and Gas Suppliers Association of Nigeria, the Petroleum Products Retail Outlet Owners Association of Nigeria, ati the Nigerian Association of Road Transport Owners, ti panupọ lati darapọ mọ iyanṣẹlodi yii bi ayipada ko ba si.

BBC gbọ pe ajọsọ naa n tẹsiwaju, a o maa bu abajade rẹ wa bo ba ṣe n lọ.

Àkọlé fídíò, "Òpó iná IKEDC ló wó lù mí lọ́dún méje sẹ́yìn, ń kò le rìn tàbí dá jẹun, ọ̀rá ni mofi ń tọ̀, mo ná N3m láti wo egbò ara mi" mi,

Fànfà ń wáyé láàrin iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote àti ẹgbẹ́ awakọ̀ epo NUPENG èyí tó fa ìyanṣẹ́lódì

Ọkọ Tirela epo meji ti wọn kun ni awọ eweko ati goolu n rin loju popo
Àkọlé àwòrán, Ọkọ Tirela epo meji

Ẹgbẹ awakọ epo NUPENG ti tẹnumọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ yoo bẹrẹ iyansẹlodi loni ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, Oṣu Kẹsan an ọdun 2025.

Ẹgbẹ NUPENG ni iyansẹlodi naa ko se lẹyin igbesẹ ileepo Dangote lati fofin de awọn awakọ ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi CNG lati mase darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ.

NUPENG n fi ẹsun kan ileeṣẹ Dangote Group pe o fẹ gba iṣẹ lọwọ awọn awakọ tanka epo pẹlu bi o ṣe dena idarapọ awọn oṣiṣẹ awakọ rẹ sinu ẹgbẹ awọn osisẹ.

Ọpọ awọn eeyan lo koro oju si igbesẹ ileeṣẹ Dangote bayii.

Dangote fẹ gba iṣẹ lọwọ wa, ko le maa se epo, ko tun maa gbe epo naa funra rẹ sita fun tita - Ẹgbẹ PTD

Igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn awakọ tanka epo (PTD), Lawal Garba sọ fun BBC pe gbogbo ohun ti Dangote n ṣe pata lo lodi si ofin.

O ni, "Pẹlu eyi, awọn awakọ tanka yoo fi iṣẹ silẹ, ti ileeṣẹ Dangote ba tẹsiwaju pẹlu ohun to n ṣe, pe ki o ma lo ọkọ ara rẹ gbe epo, a wa naa ni lati gbe gbesẹ, ki a si bẹrẹ iyansẹlodi."

Ẹgbẹ awọn to n ta afẹfẹ gaasi (NUGASA) naa ti kede atilẹyin wọn fun igbesẹ iyansẹlodi ti NUPENG gbe kalẹ.

Igbakeji aarẹ ẹgbẹ naa lorilẹede Naijiria, Abdullahi Idris sọ fun BBC pe, digbi ni awọn wa lẹyin ẹgbẹ NUPENG lati gunle iyansẹlodi.

O ni, "Ti Dangote ba fẹ maa gbe epo lọ sawọn ile epo pẹlu ọkọ rẹ nikan, ki ni a fẹ ṣe? Wọn ti le wa kuro lẹnu iṣẹ wa, eyi ti a ti n ṣe tipẹ."

Ẹgbẹ alagbata epo lorilẹede Naijiria (IPMAN) ti wa rọ ẹgbẹ mejeeji pe ki wọn wa ojutu si ọrọ yii,

Alhaji Abubakar Mai Gamji Shettima, alaga ẹgbẹ IPMAN lorilẹede Naijiria, sọ fun BBC pe awọn fẹ ki NUPENG, PTD and NARTO wa ọna abayọ to dara si aawọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Falana ṣe atilẹyin fun NUPENG

Agba Amofin kan to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana, SAN ti ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ NUPENG lori iyansẹlodi ti wọn fẹ gunle, to si fi di rẹ mulẹ pe igbesẹ ileeṣẹ Dangote tako ofin orilẹede Naijiria lori ọrọ oṣiṣẹ.

Falana ni igbesẹ yii ṣe ọpọ abuku si eto ilana agbaye ti Naijiria n tẹle, to fi mọ ofin to n se atilẹyin fun ọmọniyan lati se ẹgbẹ to ba wu, Freedom of Association and Protection of the Right to Organise Convention (1948, No. 87), the Right to Organise and Collective Bargaining Convention (1949, No. 98).

Bakan lo ni ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaye pẹlu ajọ iṣokan agbaye fun ifẹsẹmulẹ ẹtọ ọmọniyan, United Nations Universal Declaration of Human Rights, ati bẹ bẹ lọ fara mọ pe ki eeyan se ẹgbẹ to ba wu u.

"Ofin Ileeṣẹ Dangote yii tako iwe ofin orilẹede Naijiria to da lori ọrọ oṣiṣẹ ati ẹtọ ọmọniyan.

"Bi o tilẹ jẹ pe, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn orilẹede nla bii United Kingdom ati United States of America, dara pọ ẹgbẹ osisẹ to wu wọn, amọ ileeṣẹ Dangote Group pinnu lati tako awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria nitori wọn gba laaye lati gbe ina woju ofin.

"Ẹwẹ, o yẹ ki Dangote Group mọ pe ija pe ki awọn oṣiṣẹ wa ninu ẹgbẹ oṣiṣẹ jẹ eyi ti wọn ti ja, ti wọn si ti bori labẹ ijọba amunisin.

Fun idi eyi, a n ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NUPENG lati tako igbesẹ ileeṣẹ Dangote lori awọn oṣiṣẹ wọn."

Ijọba apapọ rawọ ẹbẹ si NUPENG lati mase gunle iyansẹlodi, o pe wọn si ipade

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti rọ ẹgbẹ awọn oṣiṣe epo rọbi lorilẹede Naijiria (NUPENG) lati tun ero rẹ pa nipa iyansẹlodi to gunle.

Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Muhammad Maigari Dingyadi lo pe fun eyi ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Patience Onuobia buwọlu fun awọn akọroyin.

Bakan naa lo tun rọ Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC pe ki wọn ko ọrọ ti wọn sọ sita pada, eyi ti NLC fi sọ fun awọn oṣiṣẹ lati bẹrẹ igbaradi fun iyansẹlodi lati le ṣe atilẹyin fun awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ epo rọbi.

Dingyadi ni, "Mo ti kọwe ransẹ si awọn ẹgbẹ ti ọrọ kan fun ipade lonii, Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, Oṣu Kẹsan an ọdun 2025.

Niwọn igba ti mo ti da si, mo n rawọ ẹbẹ si NUPENG lati ma gunle ero wọn lati bẹrẹ iyansẹlodi.

"Bakan naa ni mo tun rọ NLC pe ki wọn mase gunle iyansẹlodi ti wọn fẹ se lati ṣe atilẹyin fun NUPENG.

Ẹka ile epo rọbi ṣe pataki lorilẹede Naijiria, o jẹ ohun to ṣe koko fun eto ọrọ aje wa.

"Iyansẹlodi ni ẹka ile epo, koda ko jẹ ọjọ kan, o le ṣe akoba fun eto ọrọ aje. Orilẹede yii o padanu owo lasan, yoo tun fa inira fun ọmọ orilẹede Naijiria.

"Mo n rọ awọn ẹgbẹ ti ọrọ kan pe ki wọn jẹ ki alaafia jọba. Mo n fi da wọn loju pe ọrọ yii yoo ni iyanju laipẹ."