Ọ̀fọ̀ míì tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, Ridwan, ọmọ Ajileye dágbére fáyé

Aworan Ridwan Ajileye to di oloogbe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Afadapakiro

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oṣere tiata, Ridwan Olamilekan Ajileye, ọkan ninu awọn ọmọ gbajugbaja oṣere nigba naa, Yekini Ajileye, ti jade laye.

Iroyin nipa iku oloogbe naa lo bọ sita loju opo ayelujara Instagram, Afadapakiro, lọjọ Ṣatide, ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2025.

Ohun to fa iku oloogbe naa ni a ko le ti fidi rẹ mulẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Owurọ Ọjọ Ṣatide ni iṣẹlẹ naa waye niluu Osogbo nipinlẹ Osun.

Iku Ridwan Ajileye n waye lẹyin ti awọn agba oṣere meji, Peju Ogunmola ati Ibrahim Chatta padanu ọmọ wọn.

Gẹgẹ bii o ṣe wa loju opo ayelujara Afadapakiro lori Instagram, iku oloogbe naa ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to ohun ojiji fun mọlẹbi, akẹgbẹ, ọrẹ ati gbogbo agbo ere sinima lapapọ.

Afadapakiro ni "Olamilekan jẹ ọmọ to ni ọjọ ọla rere ṣugbọn iku ge ẹmi rẹ kuru, to si mu lọ ni kiakia."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

TAMPAN Osun ba BBC News Yoruba sọrọ nipa iku Ajileye

Oba Muruf Olayiwola, Alagunbelewo ti Agunbelewo to jẹ gomina fun awọn oṣere nipinlẹ Osun ba BBC News Yoruba sọrọ, to si ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ ọmọde to ni iwa irẹlẹ bo ti lẹ jẹ pe ko ba wọn ṣe ẹgbẹ oṣere.

Oba Olayiwola, nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ṣadede ni oun ri aworan oloogbe ti wọn gbe sita pe o ti ku, ti oun si gbe foonu oun pe ki oun kan si lori foonu ṣugbọn aburo oloogbe lo gbe ipe naa.

"Aburo rẹ lo gbe ipe mi, to si ṣo fun me pe, ẹgbọn oun ti ku.

"Ọmọ gidi ni, ṣugbọn nitori ko ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ, a ko mọ nnkan pupọ nipa rẹ.

"Ọpọ eeyan wa ni wọn lọ sibi eto isinku rẹ, emi o le lọ nitori mo ti jẹ ọba.

"Sango of Afrika ba mi sọrọ lori rẹ pe, koda oun si ri oloogbe naa ni ijẹta nigba to gbe iṣẹ ti wọn bẹ wa."

Ta ni Yekini Ajileye to jẹ baba fun oloogbe yii?

Aworan Oloogbe Yekini Ajileye to jẹ baba fun oloogbe Ridwan Olamilekan Ajileye

Oríṣun àwòrán, C/O Ajileye Films

Odu ni Yekini Ajileye jẹ lagbo ere sinima lorilẹede Naijiria.

Ọdun 1953 ni wọn bi agba oṣere yii, to si jade laye ninu oṣu kẹwaa ọdun 2006.

Ajileye ko ipa ribiribi ninu ere sinima, ti ọpọ awọn oṣere si tara rẹ di ilumọka.

Yato si pe o jẹ oṣere, Ajileye jẹ agba onkọtan ati oludari.

Awọn sinima rẹ ni Koto orun, Koto Aye, Eran iya Oshogbo, Buharimo omo orukan ati bẹbẹ lọ.