Ibrahim Chatta pàdánù ọmọ rẹ̀ ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta/instagram
Gbajugbaja oṣere tiata, Ibrahim Chatta ti kede iku ọmọ rẹ ọkunrin.
Ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ọhun lo gbe iroyin iku ọmọ naa soju opo ayelujara Instagram rẹ lọjọ Satide.
Ninu aworan to gbe sita, Chatta ni "Inna lillahi wa inna ilayhi raji'un. Ya Allah, iwọ lo mọ gbogbo nnkan. Sun ree ọmọ mi."
Ọpọ awọn akẹgbẹ ati ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ba kẹdun lori iku ọmọ naa.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti iroyin iku ọmọ kan ṣoṣo ti agba oṣere obinrin, Peju Ogunmola jade laye niluu Ibadan.
Iṣẹlẹ mejeeji yii lo ti sọ agbo ere sinima lorilẹede Naijiria sinu ibanujẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Chatta ti kọkọ kede ninu oṣu Kẹfa bo ṣe padanu ọmọ rẹ obinrin, to jẹ akọbi rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ọpọ awọn oṣere tiata n ba Ibrahim Chatta kẹdun
Wayi o, ọpọ awọn ọmọ Naijiiria, to fi mọ awọ ololufẹ Chatta atawọn akẹgbẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ba oṣere tiata naa kẹdun.
Lara awọn gbajumọ to n ba kẹdun ni Princess Damilola ti ọpọ mọ si Princess Comedian.
Muyideen Oladapo ti ọpọ mọ si Lalaa Dapo naa sọrọ loju opo Chatta lati ba a kẹdun.
Opeyemi Ayeola, Officer Woos, Dayo Amusa, Damilola Oni, Tobi Makinde ati ọpọ awọn mii lo n ba Ibrahim Chatta kẹdun iku ọmọ rẹ.
Ta ni Ibrahim Chatta?
Gbajumọ osere tiata ni Ibrahim Chatta, ọmọ ilu Bacita nipinlẹ Kogi nii se, ẹya Tapa Lempe si lo jẹ.
Ọjọ Ktala osu Kẹwa ọdun 1970 ni wọn bi gbajumọ osere naa, eyii tii se ọdun mejilelaadọta sẹyin.
Amọ Chatta ti pẹ nilẹ Yoruba, to si n ba wọn kopa ninu ere Yoruba loriṣiriṣi.
Gbajumọ oṣere naa lo ni ẹbun pupọ nipa iṣẹ tiata, ko si si ipa ti ko le ko ninu sinima.
Bo ti n kopa bii ọdọ, lo lee ṣe bii agbalagba, alakọwe, Babalawo ati janduku pẹlu.
Bakan naa ni Ibrahim Chatta ni ẹbun orin kikọ ati oriki ilẹ Yoruba pẹlu.
Lara awọn gbajumọ ere ti Chatta ti kopa ni Wehinwo, Alaaru, Police and Thief, Akirisore, Agboorun ati bẹẹ bẹẹ lọ.












