Àlàyé nípa àrùn Ebola, bó ṣe burú tó, àpẹrẹ rẹ̀ àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ rẹ̀

Nọọsi to n tọju arun Ebola pẹlu aṣọ idaabobo ara ẹni lọrun rẹ

Oríṣun àwòrán, BADRU KATUMBA/AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ eto ilera agbaye, WHO ti sa ipa lati kapa arun ọhun amọ titi di oni yii ko tii se aṣeyọri lati rẹyin rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Arun Ebola tun ti bẹ jade lorilẹede Democratic Republic of Congo nibi to ti gbẹmi eyan marundinlogun.

Ọdun to kọja n wọn kọkọ ṣawari arun naa lara obinrin alaboyun kan ti obinrin naa si pada jade laye latari bi awọn eroja inu rẹ ṣe kọṣẹ.

Iku obinrin yii ni igba kẹrindinlogun ti wọn yoo kede arun naa lorilẹede ọhun lati ọdun 1976 to ti kọkọ bẹ silẹ nibẹ.

Ajọ eto ilera agbaye, WHO ti sa ipa lati kapa arun ọhun amọ titi di oni yii ko tii se aṣeyọri lati rẹyin rẹ.

Lọdun 2022, arun naa milẹ titi ni Uganda, o si gbẹmi eeyan to le ni ọgbọn nibé.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2014 ni arun naa kọkọ wọ Naijiria nigba ti Patrick Sawyer to jẹ ọmọ orilẹede Liberia gbe arun ọhun wọle ni papakọ ofurufu ilu Eko, eyii to gbẹmi eeyan mẹjọ.

Arun wo gan ni Ebola ati pe bawo lo ṣe n tan kalẹ?

Gẹgẹ bii ohun ti ajọ WHO sọ,ara adan ni arun Ebola ti wa, arun naa si buru jọjọ latari bo ṣe maa n gbẹmi eeyan laipẹ ọjọ.

Ara ẹranko to ba ti ni arun naa bii inaki, adan ati ẹgbin lo ti maa n ran eeyan.

Ara adan ti wọn n pe 'fruit bat' ni arun naa ti kọkọ wọ abule kan lẹyin ti wọn fọwọ kan ẹjẹ, omi ati ara ẹran to ni arun naa ṣaaju.

Oriṣiriṣi ẹda Ebola meji lo wa, akọkọ ni Sudan ti ekeji rẹ si n jẹ Zaire.

Arun naa maa n tan lati ara ẹnikan si omiran lati ara igbọnsẹ, ẹje, eebi ati oru aru ara eni to ba ni.

Ti eeyan ba fi ara kan oku ẹni ti Ebola gbẹmi rẹ, o ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹẹ ko arun ọhun.

Awọn apẹrẹ arun Ebola

Ebola maa n mu ki ọna ọfun dun eeyan, o tun maa n ṣadede fun eeyan ni iba lairo tẹlẹ.

Ti arun naa ba ti wọ ara eeyan daadaa, irufẹ ẹni bẹe yoo maa bi, yoo si maa ṣe igbọnsẹ gburu, nigba mii ẹni to ba ni Ebola yoo maa yọ ẹjẹ jade lati idi.

Laarin ọjọ meji pere si ọsẹ mẹta ni arun Ebola fi maa n dagba lara eeyan, o si le mu awọn arun mii bii iba dani.

Omi ara awọn to ba ni arun naa ma n tete gbẹ, eyii to maa n yọri si iku wọn.

Bi o ṣe le dena arun Ebola

Ọdun 2014 ni arun naa milẹ titi julọ lagbaye ninu eyii ti ẹmi ẹgbẹrun mọkanla eeyan lọ si.

Awọn ọna wọnyii ni o fi le daabo bo ara rẹ lọwọ Ebola.

Maa fọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba

Lọra ni fifi ọwọ kan ẹni to ba ti ko arun naa tẹlẹ

Maṣe fi ọwọ tabi ara kan oku, paapaa ẹni ti o ko mọ irufẹ iku to gbẹmi rẹ

Ṣọra fun pipa, fifi ọwọ kan tabi jijẹ ẹran igbẹ

Abẹrẹ ajẹsara wa nigba kan ri fun ẹda Zaire arun naa amọ ko tii si abẹrẹ ajẹsara kankan fun ẹda Sudan.

Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe ẹni ti wọn ba tete ṣawari arun naa lara rẹ to si gba itọju to peye le ru u la.