"Wọ́n fipá gbẹ̀jẹ̀ lára mi, mi ò rówó oṣù gbà, wọ́n lù mí lálù dákú ní Libya kí orí tó kó mi yọ"

Oríṣun àwòrán, NIDCOM/X
Ohun ti oju ọdọbinrin Mercy Oluwagbenga to ṣẹṣẹ de lati Libya ri l'orilẹede naa, ẹnu rẹ ko lee sọ tan, Oluwagbenga ni ọga oun ni Libya lu oun lalu daku tori oun kọ lati fẹjẹ silẹ fun iya rẹ to n ṣaisan.
Oluwagbenga, to sọrọ lori eto The Morning Brief ileeṣẹ tẹlifisan Channels TV, ṣalaye bi o ti ha si Libya ti o si n ṣiṣẹ lai gbowo.
O ni wọn ṣe daadaa foun nibi toun ti kọkọ ṣiṣẹ fun oṣu mẹta akọkọ ni Libya, amọ, ṣadeedee ni nnkan yi pada.
''Nigba ti mo beere fun owo iṣẹ oṣu akọkọ ti mo ṣe, wọn sọ fun mi pe baba awọn lo maa sanwo fun mi to ba de.
Bakan naa lọmọ ṣori loṣu keji, wọn tun ni loṣu Kẹta ni baba awọn yoo sanwo fun mi, eyi jẹ ki n maa ro pe wọn n ba mi fowo naa pamọ ni.
Mo tun beere fun owo oṣu mi nigba ti baba wọn de loṣu Kẹta, amọ, ko sẹni to da mi lohun.
Bayii ni wọn bẹrẹ si ni gba ẹjẹ lara mi tori mama wọn ti ko gbadun,'' Oluwagbenga lo sọ bẹẹ.
Oluwagbenga ni nnkan toun kọkọ ro ni pe ayẹwo ni wọn n fi ẹjẹ ti wọn n gba lara oun ṣe tori aṣa wọn nilẹ Araabu ni ki wọn maa ṣe ayẹwo loṣu mẹta-mẹta fawọn oṣiṣẹ wọn lati le mọ bo ya ara wọn pe lati maa ṣiṣẹ lọ.
Ṣugbọn Oluwagbenga ni oun ṣakiyesi pe nọọsi to n tọju mama wọn to n ṣaisan naa lo n gba ẹjẹ oun ni gbogbo igba lai mu oun lọ sile iwosan.
O ni lẹyin naa loun ko jẹ ki wọn gba ẹjẹ oun mọ ti wọn si bẹrẹ si ni lu oun.
''Mo gbero lati salọ, ṣugbọn ko si ọna fun mi tori wọn ti mi mọle''
Oluwagbenga to jẹ ọmọbibi ilu Kabba nipinlẹ Kogi ṣalaye pe gbogbo igbiyanju oun lati wa iranwọ, pabo lo jasi.
''Mo gbiyanju lati pe ẹni to mu mi lọ sibẹ, nigba to ya ni mo gbọ pe o ti wa lẹwọn.
Mo gbero lati salọ, ṣugbọn ko si ọna fun mi tori wọn ti mi mọle nibẹ ni.
Lọjọ ti mo gbiyanju lati salọ, ilẹkun wa ni ṣiṣi silẹ tori mo n ṣiṣẹ kan ninu ile.
Mi o mọ pe wọn n ṣo mi, nibi ti mo ti n lọ ni wọn ti da mi lọna ti wọn si lu mi lalu daku.
Bayii ni wọn bẹrẹ si ni paarọ kaadi SIM to wa ninu foonu mi loṣooṣu, nnkan ti ko jẹ ki wọn gba foonu lọwọ mi ni pe wọn maa n pe sori rẹ lati beere alaafia mama wọn to n ṣaisan,'' Oluwagbenga ṣalaye.
Ẹwẹ, adari ajọ NIDCOM to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa, lu Oluwagbemga lọgọ ẹnu fun igboya rẹ.
Arabinrin Dabiri-Erewa ṣapujuwe Oluwagbenga gẹgẹ bii ẹni ti ori rẹ wa lẹyin rẹ tori ọpo lo ti ku si aṣalẹ ilẹ Araabu nigba tawọn mii si ti di awati.
Adari ajọ NIDCOM sọ pe gbigba ọna ẹburu rinrin ajo lọ silẹ okeere dabi ẹni pe eeyan fẹ ṣeku pa ara rẹ ni.
O wa rọ awọn ọdọ ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrin ajo lọ silẹ okeere lati gba ọna to ba ofin mu ṣe bẹẹ.
Bakan naa, lo tun ṣeleri pe ajọ NIDCOM yoo ṣe itọju Oluwagbenga titi ti yoo gbadun daadaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















