Aráàlú ní kí ìjọba rọjo àdó olóró síbùba àwọn ajínigbé lẹ́yìn ikú baba àti ọmọ ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn eniyan ijọba ibilẹ Patiki ni ipinlẹ Kwara, ti ke si ijọba lati dari awọn agbofinro ki wọn rọjo ado oloro si ibuba awọn ajinigbe to wa ni agbegbe naa, ki wọn si jẹ ibẹ run patapata.
Eyi waye lẹyin ti iroyin gbee pe awọn agbebọn kan ti wọn to meje niye yabo Mọsalasi kan ni ilu Lade ni ijọba ibilẹ Patigi, ti wọn si pa baba ati ọmọ rẹ nigba ti wọn kirun tan.
Lọjọru, ọjọ kẹta osu Kẹsan an, BBC News Yoruba kan si ọkan lara olugbe agbegbe naa, iyẹn ọgbẹni Ahmed Al-Hassan lati mọ bi o se sẹlẹ gan-an.
Ọgbẹni Al-Hassan sọ pe, ibuba awọn agbebọn ti wọn maa n gbe awọn eniyan sa lọ lẹhin ti wọn ba ji wọn gbe tan wa ni inu igbo ni agbegbe awọn.
O sọ pe, "awọn agbofinro si mọ ibuba yii, ti wọn ba parapọ, ti wọn si pinnu, ti wọn rọjo ado oloro si ibuba yii, awọn agbebọn yii yoo salọ, ko si ni si ijinigbe mọ.
"Lotitọ, awọn ijọba n gbiyanju, sugbọn igbiyanju naa ko to nitori ko ka oju ẹ.
"Titi di akoko yi, awọn sọja si wa ni awọn agbegbe wa, lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan, a si mọ pe ijọba naa lo ko wọn wa.
"Sugbọn, ki wọn lọ si ibuba wọn, ki wọn si jẹ ibẹ run, lo le mu opin de ba iwa ijinigbe ati ipaniyan to gbode kan.
Ohun tí aráàlú sọ nípa ikú àwọn méjèèjì ọ̀hún
Lori baba ati ọmọ ti awọn agbebọn naa pa, Ọgbẹni Hassan salaye pe baba ti wọn n pe ni Alhaji Gomina Lade ati ọmọ rẹ ni wọn kirun Ishai tan ninu Mọsalasi lalẹ ọjọ naa ni ilu Lade, wọn si n pada lọ si ile.
O sọ pe, "bi wọn ṣe jade ni wọn gbọ girigiri awọn ọdaran yii, wọn si yinbọn fun wọn, baba ku lẹsẹkẹsẹ, sugbọn wọn gbe ọmọ de ile iwosan ki oun naa to dagbere faye lọjọ keji.
"Alhaji Gomina Lade dagba to ẹni aadọrin ọdun, awọn kan sọ pe wọn fẹ jii gbe ni sugbọn o ṣe e ṣe ko jẹ pe wọn diidi wa baba naa wa lati paa ni.
"Idi ni pe, o jẹ ọkan lara awọn eeyan pataki niluu, o si maa n gbọ iroyin daada nipa awọn agbebọn leyi to maa n fi to olori ilu leti loore-koore lati le wa ni igbaradi ati imurasilẹ fun awọn aṣebi yii.
"Emi lero pe idi niyii ti wọn fi seku paa ki o ma ba le di wọn lọwọ isẹ wọn mọ.
"Ni ti awọn eeyan wa, wọn ti gba fun Olorun, wọn kan n rawọ ẹbẹ si ijọba naa ni pe ki wọn gba awọn.
Ìgbésẹ̀ ọlọ́pàá
Bakan naa ni BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Kwara, Arabinrin Ejirẹ Toun Adeyemi, to fidi ọrọ naa mulẹ.
O ni kete ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni awọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, awọn si ba awọn korofo ọta ibọn tawọn agbebọn naa yin.
O sọ pe, iṣẹlẹ naa waye ni ọgbọnjọ osu Kẹjọ ọdun 2025 lasiko irun Ishai.
O fi kun pe iwadii n lọ lọwọ lati mu awọn onisẹ ibi naa.
Arabinrin Adeyemi ṣe alaye pe ajọ ọlọpaa Kwara labẹ idari CP Adekimi Ojo n sisẹ lai saarẹ lati mu ijinigbe ati ipaniyan dopin ni Kwara.
O ni lootọ ni ijinigbe ati ipaniyan yii jẹ ohun to n ba orilẹede finra lasiko yii ti kii si se Kwara nikan.
O ni ajọ ọlọpaa Kwara n sisẹ papọ pẹlu awọn ajọ alaabo mii lati rii pe awọn aṣebi yii jina rere si ipinlẹ naa.















