Ọdún egúngún di yánpọnyánrin nílùú Eko, èèyàn mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọn

Oríṣun àwòrán, Naij.com
O to eeyan mẹta ti wọn pàdanu ẹmi wọn lasiko ọdun eegun to bẹrẹ ni Ọjọ Aiku ni agbegbe Lagos Island nipinlẹ Eko.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ti ṣafihan ohun pato to ṣokunfa iṣẹlẹ naa, bo ti lẹ jẹ pẹ ọpọ gbagbọ pe awọn ẹgbẹ okunkun lo ya wọ ibi ti ayajọ naa ti waye.
Olugbe agbegbe to ba ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch ni iṣẹlẹ naa di yanpọnyanrin lẹyin ti ọdun eegun naa pari.
"Bi a ṣe pari ọdun eegun naa ni ija bẹ silẹ laarin awọn ọdọmọkunrin ti wọn pe ni ẹgbẹ okunkun. Ki a to mọ, wọn bẹrẹ si ni ma ju igo si ara wọn, ti wọn si n yọ ohun ija oloro.
"Ko si ẹnikẹni ninu wa to le duro lasiko naa, ọpọ wa si ni lati sa asala fun ẹmi wa ni," olugbe naa ṣalaye.
Olugbe mii to pe orukọ rẹ ni Kazeem ni ija naa waye fun ọpọ wakati, ti ọpọ olugbe si ni lati ṣa aṣala.
"Ija yii ni irọlẹ titi wọ ooru. Ọpọ ninu wa ko le sun nitori rogbodiyan yii ati bi ariwo se pọ," o ṣalaye.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ninu atẹjade ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ naa lọjọ Isẹgun kede pe awọn ti fikun aabo ni agbegbe Lekki, Ajah ati awọn agbegbe bii Ogombo ati Elemoro.
Igbesẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gbe kalẹ lati pe fun alaafia ni agbegbe ti ọrọ kan.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe ọpọ awọn ọlọpaa lo ti wa ni awọn agbegbe yii lati ri daju pe alaafia jọba.
Ileeṣẹ ọlọpaa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe eeyan mẹta ọtọtọ padanu ẹmi wọn lasiko ọdun Egungun yii to waye ni agbegbe Lekki Phase 1.
Bakan naa ni Hundeyin fidi rẹ mulẹ pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹtalelogun lori iṣẹlẹ naa.
"Awọn afurasi naa ni Frank Okpara (27), Friday Ebuka (27), Babatunde Mufutau (24), Suleiman Muri (25), Olamide Malik (24), Nwaka Lucky (34), Raphael Ashim (30), Wasiu Kareem (33), Sadiq Olabisi (40), Ibrahim Abdul (22), Ibrahim Aminu (37), Nasiru Musa (27), Friday Nwafor (51), Ahmed Fatai (26), Aro Abiola a.k.a. Zino (25), Tijani Shehu a.k.a. Abana (26), Gift Igedi (31), Ugochukwu Chike (30), Ridwan Alex (37), Happiness Otigbo (27), Abiodun Adegun (37), Adedayo Adeoti (27), atiAfeez Ahmed (31).
"Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, Eko Strike Force ti balẹ si agbegbe Lekki ati Ajah lati ri daju pe ko I rogbodiyan kankan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















