Ó tún ti ń rúgbó bọ̀ l'Ogbomosho, Ṣoun Ghandi Laoye ń forígbárí pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọbíbí ìlú Ogbomosho kan

Ọba Ghandi Laoye

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awuyewuye mii tun ti ṣẹyọ niluu Ogbomoso lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ti Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta, ti tuka ke gbajare wi pe kabiesi naa ko lagbara lati tu igbimọ naa ka.

Ninu fọnran kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi T.M. Balogun, alaga abẹle ẹgbẹ naa, Alhaji Iliasu Jamiu ati ati akọwe abẹle, Arabinrin Janet Akintoyinbo fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ iroyin ni wọn ti ṣalaye pe igbesẹ Ọba Olaoye tako iwe ofin ati ilana ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.

Awọn oloye ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ko tabuku tabi ṣe arifin si kabiyesi, ṣugbọn awọn n tẹle nnkan to wa ninu ofin ẹgbẹ naa ni.

Awọn oloye ẹgbẹ naa wa sọ fawọn ọmọbibi ilu Ogbomoso nile loko ati lẹyin odi wi pe awọn si wa nipo awọn gẹgẹ bii igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.

Wọn ni igbesẹ Ọba Olaoye lati tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ọhun ka ju agbara kabiyesi naa lọ.

Awọn oloye naa sọ ninu fọnran ti wọn fi sita naa wi pe ''Ọba ko ni agbara lati tu ẹgbẹ wa ka.

Ko si ninu iwe ofin ẹgbẹ wa bẹẹ, nitori naa, gbogbo awa oloye ẹgbẹ si wa ni ipo wa.

A ko fi eyi tabuku kabiyesi, bi ko ṣe wi pe a duro lori nnkan ti iwe ofin wa sọ lọ ni.''

Idi ti Soun Ọba Ghandi Olaoye fi tu igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ka

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọsẹ to kọja ni Kabiyesi Ọba Ghandi Olaoye to jẹ baba isalẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye kede pe oun ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka.

Kabiyesi si gbe igbimọ fidihẹ kan dide eyi ti Ọjọgbọn Olusegun Ajiboye to jẹ akọwe agba ẹgbẹ to n ri si iforukọsilẹ awọn olukọọ, TRCN, tẹlẹ jẹ adari rẹ.

Igbimọ yii ni ori ade naa sọ pe yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọwọ yii.

Ọba Olaoye ni oun tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka fun atunto ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ki ẹgbẹ naa le wa ni ibamu pẹlu eto idagbasoke ọlọdun mẹẹdọgbọn oun fun ilu Ogbomoso.

Amọ, ọpọ lo ti n sọ pe igbesẹ kabiyesi ko ṣẹyin ibaṣepọ ori ade naa ti ko dan mọran pẹlu awọn oloye ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye, eyi to jẹ ki ọpọ ninu wọn jinna si aafin.

Iroyin kan tiẹ fidi rẹ mulẹ wi pe aarẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye tẹlẹ to doloogbe loṣu Kẹfa ọdun yii, Adajọ fẹyinti Afolabi Adeniran, kuna lati wa ojutuu si faakaja to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.

Iroyin naa sọ pe eyi gan an lo jẹ ki kabiyesi gbe igbesẹ to gbe tori o dabi ẹni pe awọn kan ti fẹ ja ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye gba.

Ọrọ Aafin Ogbomoso lori ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye

Oríṣun àwòrán, Aafin Ogbomoso

Ọrọ Aafin Ogbomoso lori ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye

Oríṣun àwòrán, Aafin Ogbomoso

Ọrọ Aafin Ogbomoso lori ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye

Oríṣun àwòrán, Aafin Ogbomoso

Ọrọ Aafin Ogbomoso lori ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye

Oríṣun àwòrán, aafin Ogbomoso